Ẹ wo oju Lekan Adekanbi, afurasi to lọwọ ninu bi wọn ṣe dana sun ọkọ atiyawo l'Abẹokuta lọjọ ọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 8, 2023

Ẹ wo oju Lekan Adekanbi, afurasi to lọwọ ninu bi wọn ṣe dana sun ọkọ atiyawo l'Abẹokuta lọjọ ọdun


Lekan Adekanbi, afurasi kan ṣoṣo ti wọn loo lọwọ ninu iku tọkọ tiyawo kan t'awọn amookunṣeka pa danu, ti wọn tun dana sun oku wọn mọ inu ile niluu Abẹokuta lọjọ ọdun ni ẹ n wo yii.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Lekan ti na papa bora nibi to ti n gba itọju lọwọ lahaamọ ọlọpaa ẹkun Ibara niluu Abẹokuta.
 
A gbọ pe ọwọ tẹ Lekan, lẹyin ti ẹnikan ti ori ko yọ nibi ikọlu ọhun naa sọ pe o mọ nipa bi wọn ṣe pa awọn eeyan naa danu, ti wọn tun lọ ju ọmọ kan ṣoṣo to ku laye sinu odo.
 
Lẹkan ni wọn lo ṣebi ẹni to daku ni kete ti ọwọ palaba rẹ segi, ti wọn si sare gbe e lọ si ọsibitu kan fun itọju.
 
Wọn ni nibi to ti n gba itọju lọwọ lo ti raaye na papa bora, lai jẹ kẹnikẹni mọ.
 
A gbọ pe Lekan lo n wa Arabinrin Olubukọnla Fatinoye gẹgẹ bi awakọ rẹ.
 
Bo tilẹ jẹ pe awa ko tii le f'idi rẹ mulẹ, lara awọn to sọrọ jẹ ko ye wa pe niṣe ni Lekan sọ fun ọkan lara awọn nọọsi naa pe oun fẹẹ tọ, ti wọn si fun un laaye lati lọ baluwẹ, lai mọ pe o ni erongba buruku lọkan lati salọ.
 
Wọn ni baluwẹ ọhun lo gba fo fẹnsi salọ, ti wọn ko si rii mọ.
 
Ẹnikan naa tun sọ pe bo ṣe ri ẹnikan yooku to wa nibi ti wọn ti ṣeku pa awọn tọkọ tiyawo naa lo ti juba ehoro, ti ọwọ ko si tẹ ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI