OGUN: Ẹ fọkan balẹ, igbadun mbọ fun yin laipẹ - Adebutu fọkan awọn oṣiṣẹ, oṣiṣẹfẹyinti atawọn araalu balẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 25, 2023

OGUN: Ẹ fọkan balẹ, igbadun mbọ fun yin laipẹ - Adebutu fọkan awọn oṣiṣẹ, oṣiṣẹfẹyinti atawọn araalu balẹ


Oludije s'ipo gomina nipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu ti sọ pe ki gbogbo awọn oṣiṣẹ, oṣiṣẹfẹyinti atawọn araalu lọ fọkan wọon balẹ nitori pe gbogbo igbadun ti wọn ti padanu lọjọ to ti pẹ lawọn n mu bọ wa fun wọn.
 
Adebutu lo sọrọ naa nibi ipade ti igbakeji rẹ, Ọnarebu Adekunle Akinlade ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn Imaamu, Leagues of Imam n'ipinlẹ Ogun laipẹ yii.

Ninu ọrọ Akinlade, o ni eto igbayegbadun araalu, paapaa awọn oṣiṣẹ, oṣiṣẹfẹyinti lo jẹ Ọnarebu Adebutu logun, eyi ti yoo fi mu lokunkundun nigba to ba de ipo gomina ti wọn n le.
 
Bakan naa lo fi da awọn eeyan loju pe gbogbo ileri tawọn ṣe lawọn yoo muṣẹ, nitori pe gbogbo rẹ lo wa ninu akọsilẹ, ati pe awọn ko nii ṣe ileri ti wọn ko ni le muṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI