Oludije s'ipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti pariwo sita wi pe gbogbo igbesẹ ti ijọba orileede yii n gbe ni lati dabaru eto idibo apapọ ọdun 2023 ti a wa yii, to si ni owo Naira tuntun ati ọwọngogo epo bẹntiroolu to wa nita lasiko yii ni wọn fẹẹ lo.
Tinubu lo tu aṣiri nla naa sita lasiko eto ipolongo idibo to ṣe niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lonii, Ojọru, Wẹsidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023.
Ipolongo idibo naa to waye ni Papa Iṣere MKO to wa lagbegbe Kutọ niluu Abẹokuta lo kun fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri ipinlẹ Ogun, to fi mọ awọn ololufẹ agba oloṣelu naa.
O ni Naira tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe jade ko si nita f'awọn araalu lati na, bẹẹ si ni awọn araalu tun n jiya fun epo bẹntiroolu, eyi to ni ijọba apapọ ṣebi ẹni pe wọn ko mọ ohun to n lọ nipa awọn ipenija mejeeji yii, nitori pe gbogbo ipinnu wọn ni lati dabaru eto idibo apapọ.
Nibẹ lo ti sọ pe ohun to da oun loju ni pe awọn ọmọ Naijiria ko nii gba, wọn yoo jade lati dibo lọpọ yanturu, nitori pe ayipada rere ni wọn n fẹ.
Tinubu, ninu ọrọ rẹ sọ pe:
"Wọn ko fẹ ki idibo yii waye. Wọn fẹẹ dabaru ẹ ni. Njẹ ẹ maa gba wọn laaye bii? Wọn ti bẹrẹ sii gbe ọrọ aisi epo rọbii dide. Ẹ ma mikan, ti ko ba si epo bẹntiroolu, a maa fi ẹsẹ wa rin lọ sibi ti a ti maa dibo, a si maa dibo wa.
"To ba wu yin, ẹ fi owo kun owo epo, ẹ tọju epo fun wa, tabi ki ẹ tun ọda ara owo naira ṣe, a maa bori ninu eto idibo to n bọ lọna yii.
"A maa fi kaadi idibo wa gba ijọba kuro lọwọ wọn. Bi wọn ba fẹ, ẹ jẹ ki wọn sọ pe ko si epo, a maa fi ẹsẹ rin lọ si ibudo eto idibo. Ẹlẹtanjẹ nla ni wọn jẹ, wọn tun le sọ pe ko si epo mọ, nitori pe wọn ti n sọrọ nipa ọwọngogo epo bayii, ẹ gbagbe ẹ jare, ẹ fọkanbalẹ. Ẹmi Aṣiwaju maa f'opin si ọwọngogo epo
"Ẹ jẹ ki owo epo tubọ maa lọ soke sii, awọn ni wọn mọ ibi ti wọn n ko epo pamọ si. Wọn n tọju owo naira tuntun, wọn tun n tọju epo, a maa dibo, a si maa bori wọn.
"To ba wu yin, ẹ tun le yi ọda ara owo naira tuntun pada, ẹ na owo ninakuna, ki ẹ si jẹ gbese, o maa ya yin lẹnu wi pe a maa bori eto idibo yii, a maa bori awọn alatako wa.
"Ọdọ ni mi, mo si wa nibi fun un yin, oju ko si nii ti yin. A maa gba ijọba kuro lọwọ wọn, ọdalẹ ni wọn ti wọn fẹẹ ba wa jijakadi lati gba ijọba lọwọ wa, wọn ko tii ṣe iru ẹ ri tẹlẹ.
"Asiko ijamgbara la wa yii. Ijamgbara ni eto idibo yii yoo jẹ. Alagabagebe ni wọn, alawada si ni wọn pẹluu. Nigba ti wọn ko ni ohun ti wọn fẹẹ sọ, niṣe ni wọn n tọju epo, wọn n sọ pe epo maa di igba ati ẹẹdẹgbẹta naira, ṣugbọn ṣa, ẹ fọkanbalẹ, a maa f'opin si ọwọngogo epo, a maa f'opin si wahala aisi epo."
No comments:
Post a Comment