Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin ti sọ ọ di mimọ pe ojoojumọ lawọn eeyan n pe oun wi pe awọn fẹẹ darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa, nitori ti wọn lo wu awọn pupọ.
O lawọn to n pe oun sọ pe awọn fẹẹ finu-fẹdọ lati darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa ni, nitori pe iwuri ni iṣẹ naa n jẹ f'awọn.
Hundeyin sọ pe yatọ si pe awọn kan n pe oun, o lawọn miran tiẹ tun maa n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ soun lori foonu lati maa beere fun anfaani lati darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa.
Bẹẹ lo ni wọn ba n bẹ oun lati beere igba ti fọọmu iṣẹ ọlọpaa yoo jade, ti wọn si maa n ni koun fi to wọn leti.
Hundeyin lo tu aṣiri naa sita loju opo Twitter rẹ laipẹ yii, to si tun fi asiko naa lati dupẹ lọwọ gbogbo awọn to nifẹẹ si iṣẹ ọlọpaa.
O ni;
O ni;
“Ṣ ẹ n mu mi ṣere ni?
“Lojoojumọ, mo n gba ipe ati atẹjiṣẹ loriṣiriṣi, ti awọn eeyan n beere pe, ‘Igba wo ni fọọmu iṣẹ ọlọpaa yoo jade? Awọn nifẹẹ sii lati darapọ mọ ọlọpaa.’
“Emi si n ro pe gbogbo eeyan lo korira ọlọpaa@PoliceNG
“Mo dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin wa kaakiri”
No comments:
Post a Comment