Idibo 2023: Ẹnikẹni to ba gbe ayederu iroyin jade yoo fẹnu-fẹra bi abẹbẹ - Ileeṣẹ ọlọpaa Eko - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 15, 2023

Idibo 2023: Ẹnikẹni to ba gbe ayederu iroyin jade yoo fẹnu-fẹra bi abẹbẹ - Ileeṣẹ ọlọpaa Eko


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ wi pe o gbe ayederu iroyin jade lakoko yii yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ, lẹyin to ba foju winna ofin.
 
Ọga ọlọpaa Abiọdun Alabi lo sọ eyi di mimọ nibi idanilẹkọọ to ṣe pẹlu awọn akọroyin to n kọ nipa iṣẹlẹ ọdaran.
 
Nibẹ lo ti sọ pe ki gbogbo awọn to n gbe iroyin ti wọn kii f'idi rẹ mulẹ jade lọ dẹkun iwa naa, to si ni ki wọn yago fun gbogbo ohun to le mu wọn foju winna ofin.
 
Alabi jẹ ko di mimọ pe ijamba to wa ninu ayederu pọ pupọ, ko si ni anfaani kan to n ṣe fun ilu, bi ko ṣe pe ko dori ilu ati orileede kodo, ati pe o tun maa n fa ogun wọnu ilu.
 
Bakan lo sọ pe awọn ko nii gba ayederu iroyin laaye lakoko eto idibo ọdun 2023 to n bọ lọna yii, ati pe gbogbo ọna lati dẹkun ayederu iroyin to le dabaru eto idibo 2023 ru lawọon ti n ṣiṣẹ lori ẹ.
 
Nibẹ lo ti rọ awọn agba akọroyin lamọran lati maa ṣe iwadii kikun ko to di pe wọn gbe iroyin wọn jade, ki wọn ma si ṣe kanju lati gbe iroyin wọn jade.

Lara awọn to tun sọrọ nibi idanilẹkọọ naa ni ọga agba fun ajọ eleto idibo nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Oluṣẹgun Agbaje; awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ l'Ekoo, ileeṣẹ eleto aabo Sifu Difẹnsi l'Ekoo, ẹgbẹ akọroyin l'Ekoo, ileeṣẹ to n ṣakoso eto igbohunsafẹfẹ (NBC), ẹgbẹ Inter-Party Advisory Council Nigeria (IPAC), Nigerian Bar Association (NBA), Center for Democracy and Development (CDD), Police Community Relations Committee (PCRC) ati Police Eminent Persons Forum (PEPF).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI