Ojulari to fẹẹ da ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC ru ni Kwara ti foju ba ile-ẹjọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 31, 2023

Ojulari to fẹẹ da ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC ru ni Kwara ti foju ba ile-ẹjọ


Ogbologbo tọọgi tọwọ palaba rẹ segi laipẹ yii niluu Ilọrin, Abọlaji Shaffi, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Ojulari ti f'oju ba ile-ẹjọ lori ẹsun wi pe o fẹẹ da eto ipolongo idibo ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ru.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni ọwọ tẹ Ojulari pẹlu ibọn, lakoko to fẹẹ da wahala silẹ lati dabaru ipolongo ibo tẹgbẹ APC ṣe lagbegbe Ojuẹkun/Sarumi to wa niluu Ilọrin.
 
 
 
Nigba to n f'oju ba ile-ẹjọ Majisireeti, niwaju Onidajọ Adam Mohammed, o loun ko jẹbi pẹlu alaye.
 
Bo tilẹ jẹ pe Onidajọ Mohammed ti paṣẹ pe ki wọn ṣi lọ fi Ojulari pamọ sọgba Oke Kura titi di ọjọ kọkanlelogun, oṣu keji, ọdun 2023 ti igbẹjọ miran yoo tun waye, sibẹ, ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe awọn ko fẹ ki wọn fi silẹ, nitori pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ni.
 No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI