Ọladele to gun ọkada, ti ko si fẹẹ san owo f'ọlọkada dero ile-ẹjọ l'Ado-Ekiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 28, 2023

Ọladele to gun ọkada, ti ko si fẹẹ san owo f'ọlọkada dero ile-ẹjọ l'Ado-Ekiti


Kani gendekunrin ọmọ ọdun mẹtalelogun nni, Ọladele Tosin mọ pe iwa toun hu yoo pada gbe oun de ile ẹjọ ni, boya ko ba ti jokoo silẹ rẹ, ko si maa sun jẹjẹ, eyi ti ko fi ni ko si wahala afọwọfa.
 
Jẹjẹ ni wọn sọ pe wahala jokoo, ko to di pe Ọladele lọ tọọ n'ija, to si pada jẹ pe ile ẹjọ ni ọrọ rẹ pada gbẹyin si, nibi to ti n bẹbẹ fun ẹyinju aanu.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii ni Ọladele foju ba ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ado-Ekiti, ipinlẹ Ekiti lori wi pe o gun ọkada, ko si fẹẹ san owo fun ọlọkada to gbe e.

Nnkan aago mejila ọsan, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejilelogun ni Ọladele pe ọlọkada, ti wọn si ni agbegbe meje ọtọọtọ ni ọlọkada naa gbe Ọladele lọ ko to di pe o fẹẹ yọnda rẹ lati maa lọ ni nnkan bi aago kan aabọ ọsan ọjọ naa.

Wọn ni nigba ti Ọladele bọ silẹ lati maa lọ ni ọlọkada naa beere owo rẹ, to si ni ẹgbẹrun mẹta naira loun yoo gba, ṣugbọn kaka ki Ọladele fun un lowo, niṣe lo sọ pe ko maa lọ, oun ko lowo kankan lọwọ.

Niṣe ni wọn lọrọ naa dabi awada loju ọlọkada, eyi to mu ko bọ silẹ tii, to si loun yoo gba owo oun. Pẹlu ibinu ni wọn sọ pe Ọladele fi koju ija si ọlọkada yii, ko to di pe awọn eeyan sare lọ sibẹ lati da sii.

B'awọn eeyan ṣe ri b'ọrọ ṣe ri, lo jẹ ki wọn ranṣẹ pe awọn ọlọpaa lati fi to wọn leti,
 
Agbefọba Bamikọle Ọlasunkanmi, to fẹsun mẹrin ọtọọtọ kan Ọladele niwaju Onidajọ Saka Afunṣọ sọ pe iwa naa tako iwe ofin ọdaran ti abala 181, 338, 416, to si ni ijiya loju iwe 183 ati 184 ti iwe ofin ipinlẹ EKiti lọdun 2021.
 
Nigba to n sọrọ, Onidajọ Saka Afunṣọ wa sun igbẹjọ siwaju di ọgbọn, ọjọ, oṣu yii, to si ni ki wọn gba oniduro fun Ọladuro pẹlu ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI