Oludije lẹgbẹ ADC binu fẹgbẹ silẹ ni Kwara, o loun ti ba APC lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 12, 2023

Oludije lẹgbẹ ADC binu fẹgbẹ silẹ ni Kwara, o loun ti ba APC lọ


Ṣe ni pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Action Democratic COngress, ADC nipinlẹ Kwara la ẹnu silẹ, ti wọn ko si fẹẹ le pa a de nigba ti ọkan lara awọn oludije sipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa binu fẹgbẹ silẹ, to si loun ko dije du ipo mọ labẹ asia ẹgbẹ naa.
 
Ishaq Issa Alawuyan lorukọ oludije naa, ẹni ti wọn lo ti gba fọọmu, o si ti n polongo kaakiri wi pe k'awọn eeyan dibo f'oun, ṣugbọn lojiji lo sọ pe ẹgbẹ oṣelu ADC toun fẹẹ ba jade ti su oun.
 
Wọn lo sọ pe oun ko ri ọjọ iwaju rere lẹgbẹ ADC mọ, to si loun ti fi ọkan papọ soju kan lati tẹle ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni ọkan lara awọn oludije ẹgbẹ oṣelu Labour naa sọ pe oun ko jade du ipo mọ lẹgbẹ naa, toun naa si loun ti ba APC lọ.
 
Agbegbe Ipaye/Malete/Oloru la gbọ pe Alawuyan fẹẹ ṣoju nile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, ko to sọ pe oun ti juwọ silẹ fẹgbẹ APC, nitori pe ẹgbẹ to n ṣanfaani lọwọ fun Kwara ni.
 
O ni o ti di dandan foun lati polongo ibo fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, ko le pada s'ipo naa lẹẹkeji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI