Ọmọ ọdun mẹtalelogun to tan obinrin-oyinbo lọ si Ilọrin lati luu ni jibiti abẹ ati owo ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 15, 2023

Ọmọ ọdun mẹtalelogun to tan obinrin-oyinbo lọ si Ilọrin lati luu ni jibiti abẹ ati owo ti ha o


Ṣikun bayii lọwọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara tẹ gendekunrin, ọmọ ọdun mẹtalelogun kan, Awolẹyẹ Joshua Oluwatofunmi, ẹni ti wọn lo tan obinrin oyinbo ilẹ Amẹrikan kan,
Vonapolouis Moss.

Ẹgbẹrun kan owo dọla ($1,000) la gbọ pe Josuha ti gba lọwọ Moss ko to di pe aṣiri rẹ tu.

AWIKONKO gbọ pe ori ikanni ayelujara ti TikTok ni awọn mejeeji ti pade, ti wọn si ni Joshua pe orukọ rẹ ni Howard Adams fun Moss, ati pe ọmọ ilẹ Amẹrika loun.

Wọn ni lẹyin aṣoyepọ ni Joshua sọ fun Moss lati wa ki oun ni Naijiria toun ti wa ṣe faaji, eyi to jẹ ki obinrin naa gbera kuro nibi to n gbe ni 2962, W 64th Court, Merrillville, Indiana 46410, USA.
 
Ọjọ kẹsan, oṣu kinni, ọdun yii ni Moss de si papakọ ofurufu ti Murtala Mohammed to wa ni Ikẹja niluu Eko, ko to di pe o wọ baluu miran lọ siluu Ilọrin, nibi to ti lọ pade Joshua.
 
Ọjọ kẹta tii ṣe Furaide to kọja yii la gbọ pe ọwọ tẹ Joshua to n gbe lagbegbe Sabo-Oke niluu Ilọrin.
 
Gẹgẹ bi ọga ọlọpaa Kwara, Paul Odama ṣe ṣalaye f'awọn akọroyin, o ni nnkan bi aago mejila, ọsan lọwọ tẹ Joshua nibi to ti n lu obinrin oyinbo naa ni jibiti ni otẹẹli kan to wa lagbegbe Flower Garden, Ilọrin.
 
Ọdama sọ pe awọn kan lo ta awọn lolobo, ti wọn fi ṣe iwadii naa. O ni iwadii naa pada so eso rere fun wọn, nigba tọwọ tẹ Joshua, to si jẹwọ pe otitọ ni, ati pe oun kabamọ iwa naa.
 
Bakan naa lo jẹ ka mọ pe awọn ti kan s'awọn ileeṣẹ tọrọ kan, ati pe awọn ti gba obinrin naa kuro lọwọ Joshua, ẹni to yan iṣẹ jibiti ori ayelujara, Yahoo-Yahoo laayo.

Siwaju sii lo sọ pe igbesẹ ti n lọ lati rii pe wọn da obinrin naa pada sibi to ti wa.


 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI