Ọpẹ o! Ile ẹjọ agba lorileede Naijiria paṣẹ pe Aderinokun ni ojulowo oludije sipo aṣofin agba ni PDP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 26, 2023

Ọpẹ o! Ile ẹjọ agba lorileede Naijiria paṣẹ pe Aderinokun ni ojulowo oludije sipo aṣofin agba ni PDP


Ile-ẹjọ agba (Supreme Court) lorileede Naijiria, eyi to wa niluu Abuja ti paṣẹ Olumide Aderinokun ni ojulowo oludije sipo aṣofin agba lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.

Oni tii ṣe Ọjọbọ, Tọsidee ni idajọ naa waye, nigba ti ile ẹjọ agba naa ti idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to ti kọkọ waye lẹyin wi pe Aderinokun ni ojulowo oludije sipo aṣofin agba labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa.

Ẹnikan ti wọn pe ni Dada Kọlawọle Ọduntan lo gbe ẹjọ naa lọ si kootu wi pe wọn yan oun jẹ ninu eto idibo abẹle ti ẹgbẹ naa ṣe, ati pe oun gan-an l'awọn eeyan n fẹ, bẹẹ lo sọ pe ọna ẹburu ni wọn gba yan Aderinokun.

Ṣugbọn gbogbo ile ẹjọ ti ọkunrin naa lọ patapata lo ti lulẹ, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe ko si otitọ kankan ninu ẹjọ to pe si kootu.

Bẹ o ba gbegbe, ile ẹjọ giga tijọba apapọ to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ti kọkọ da Ọduntan lare ẹjọ to pe fi tako yiyan ti wọn yan Aderinokun gẹgẹ bi ọmọ oye s'ipo naa.

Onidajọ Oguntoyinbo lo da ẹjọ naa, to si paṣẹ pe ki ajọ INEC yọ orukọ gbogbo awọn oludije to wa ni igun oludije sipo gomina, Ọladipupọ Adebutu kuro ninu iwe idibo, ki wọn si lọ ṣeto idibo miran.

Lẹyin eyi ni wọn pe ẹjọ kotẹmilọrun niluu Ibadan.

Ninu oṣu kejila, ọdun 2022 ni ile ẹjọ kotẹmilọrun tijọba apapọ to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ti yi ẹjọ ti ile ẹjọ giga tijọba apapọ to wa niluu Abẹokuta ti kọkọ da danu, wi pe idajọ naa ko t'ọna.

Bẹ o ba gbegbe, ibo 214 ni Aderinokun ni ninu ibo 216 ti wọn di lakoko idibo abẹle to waye l'oṣu karun-un, ọdun 2022.

Nigba to n sọrọ lẹyin idajọ naa, Aderinokun sọ pe idajọ ododo lo waye, to si jẹ oriire nla fawọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun lapapọ.

"A dupẹ pe idajọ to gbẹyin yii ti fi opin si gbogbo iyemeji to le maa waye nipa jijẹ ọmọ oye mi.

"Idajọ naa jẹ orin aladun si eti gbogbo awọn eeyan n'ijọba ibilẹ Ọdẹda, Ifọ, Ewekoro, Ọbafẹmi-Owode, Abẹokuta South ati Abẹokuta North.

"O tun jẹ anfaani igbaradi wọn lati dibo fun PDP si ipo agbara nipinlẹ Ogun.

"Awọn eeyan ti duro ti wa digbi, a si gbagbọ nipa oore ọfẹ Ọlọrun, wi pe a maa bori ninu eto idibo to n bọ yii, ti a si maa yin Ọlọrun logo."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI