Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi ti tẹ gendekunrin, ọmọ ọdun mọkanlelogun kan, Umar Abubakar to lọ ra ibọn jọ sinu ile.
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Ahmed Mohammed Wakil, lo fidi iroyin ọhun mulẹ lonii, Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣi kinni, ọdun 2023.
Wakil sọ pe awọn ọlọpaa ẹkun Toro ni wọn rọwọ to Abubakar lakoko ti wọn n ṣiṣẹ kọja lọ nitosi abule Nabardo, ijọba ibilẹ Gamawa.
O ni ẹgbẹrun marundinlọgbọn ni Abubakar ra ibọn kan lọwọ ọrẹ ẹ, Mohammed lati ipinlẹ Nasarawa. O ni ibọn meji ọtọọtọ lọmọkunrin naa ra lọwọ ọrẹ rẹ.
Bakan naa lọ sọ pe oun ti yin ọta ibọn kan ninu ọta ibọn toun ra pẹlu awọn ibọn yii lakoko toun n le darandaran to wọnu oko oun lati fi maalu jẹ ẹ.
No comments:
Post a Comment