O ma ṣe o! Ile gbajumọ Kọminṣanna nipinlẹ Ogun jona di eeru l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 19, 2023

O ma ṣe o! Ile gbajumọ Kọminṣanna nipinlẹ Ogun jona di eeru l'Abẹokuta


Ibanujẹ nla l'Ọjọru, Wẹsidee ọsẹ yii jẹ pẹlu bi ile Kọmiṣanna f'ọrọ eto iṣẹ agbẹ, Ọmọwe Samson Adeọla Ọdẹdina ṣe jona.

Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la ko tii le fidi ohun to fa ijamba ina naa mulẹ, ṣugbọn a gbọ pe ile naa jona kọja sisọ

Lara awọn to gbe iroyin naa si wa leti sọ pe ko si dukia kan ṣoṣo ti wọn ri mu jade ninu ile naa to wa lagbegbe Kemta Housing Estate, Idi-Aba niluu Abẹokuta.

Ẹpa ko boro mọ nigba ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana yoo fi debẹ lati ṣe iranwọ.

Gbogbo awọn ololufẹ baba naa to ti figba kan ri jẹ ọga ile ẹkọ gbogboniṣe nipinlẹ naa ni wọn ti n ba a kẹdun, ti wọn si n fi ọrọ itura ranṣẹ sii.

Ile naa ati gbogbo ohun to bajẹ nibẹ ni wọn loo le ni miliọnu meedogun naira.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI