Ṣọọsi CAC ni wọn ti sọ pe ki n yi orukọ mi kuro ni Toyin Aimakhu - Toyin Abraham - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 12, 2023

Ṣọọsi CAC ni wọn ti sọ pe ki n yi orukọ mi kuro ni Toyin Aimakhu - Toyin Abraham


Gbajugbaja oṣerebinrin ti aye n gba tiẹ lasiko yii, Toyin Abraham ti sọ idi pataki to fi yi orukọ baba rẹ to n jẹ tẹlẹ kuro ni Aimakhu si Abraham, to si ni ṣọọṣi ni wọn tun ti jiṣẹ f'oun.
 
Toyin Abraham to n gbe fiimu rẹ to ṣẹṣẹ ṣe, Ijakumọ kaakiri ibi ti wọn ti n wo fiimu, iyẹn Cinema kaakiri agbaye lo sọrọ naa laipẹ yii, to si ni kii ṣe ohun toun lero tẹlẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:

"Orukọ mọlẹbi baba mi ni Aimakhu, eyi ti a ge kuru ninu Aimakhumẹ, to si tunmọ si 'o kan n le mi lai nidii (you are just chasing me for nothing.)
 
"Awọn eeyan ti sọ fun wa laimọye igba tipẹtipẹ wi pe ka yi orukọ naa pada, ṣugbọn mi o da wọn lohun nitori pe mo ti bẹrẹ iṣẹ tiata pẹlu orukọ naa.

"Gbogbo awọn ẹgbọn mi lo ti lọ sile ọkọ nigba yẹn, wọn si ti n jẹ orukọ ọkọ wọn. Ọmọ ọkunrin kan ṣoṣo ti a ni ninu ẹbi wa ti yi orukọ tiẹ pada si David Abraham.

"Lọjọ kan ni iran kan wa fun mi; pasitọ kan ninu ijọ CAC (Christ Apostolic Church) lo sọ fun mama mi wi pe ki wọn sọ fun mi lati yi orukọ mi pada. Pasitọ naa sọ pe orukọ ọhun ko dara to fun mi.

"O ni awọn eeyan yoo maa jowu mi lai nidii. Eyi lo si n ṣẹlẹ si pupọ awọn eeyan ti wọn fi n yi orukọ wọn pada. Igbe aye mi yi pada si rere latigba ti mo ti yi orukọ mi pada."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI