Ẹ ma fi oṣelu ba orukọ wa jẹ o - Awọn alaṣẹ fasiti Ilọrin pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 12, 2023

Ẹ ma fi oṣelu ba orukọ wa jẹ o - Awọn alaṣẹ fasiti Ilọrin pariwo sita


Awọn alaṣẹ fasiti tiluu Ilọrin to wa n'ipinlẹ Kwara ti pariwo sita wi pe awọn ko fẹ ki awọn oloṣelu lo oṣelu to wa nita lakoko yii lati fi ba orukọ awọn jẹ, tabi wọ wọn wọnu oṣelu to n lọ lọwọ.
 
Ninu atẹjade ti wọn gbe jade laipẹ yii ni wọn ti sọ bẹẹ.
 
Atẹjade ọhun ko ṣai waye, bi ko ṣe ti iroyin kan to n lọ kaakiri ori ayeljura wi pe awọn alaṣẹ naa bu ẹnu atẹ lu ijọba Kwara wi pe awọn ni wọn ṣokunfa ipenija igbokegbodo ọkọ t'awọn akẹkọọ fasiti naa n koju.

Iroyin ori ayelujara kan ti wọn pe ni factnewsng.com ni wọn lo gbe iroyin naa jade wi pe awọn alaṣẹ mu ẹnu atẹ lu ijọba Kwara, eyi ti wọn lawọn ko sọ ohun to jọ bẹẹ rara.

Wọn ni erongba ẹni to ni iroyin ayelujara naa lo gbe jade, kii ṣe ohun to wa lati ọdọ awọn, ti wọn si ni ẹni naa fẹẹ lo oṣelu lati fi ba orukọ awọn jẹ ni.
 
Atẹjade naa ree:


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI