Wọn fi AbdulRazaq jẹ oye 'Akorede ilu Oro' ni Kwara, wọn tun ṣeleri atilẹyin saa keji fun un - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 15, 2023

Wọn fi AbdulRazaq jẹ oye 'Akorede ilu Oro' ni Kwara, wọn tun ṣeleri atilẹyin saa keji fun un


Ẹsẹ ko gbero lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii niluu Oro to wa nipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti fi Gomina Abdurahman AbdulRazaq jẹ oye tuntun, iyen Akorede tiluu Oro.

Orin idupẹ l'awọn araalu naa mu sẹnu fun gomina wọn, ẹni ti wọn lo ti ko ipa to pọ ninu eto idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ Kwara, paapaa ilu Oro.

Nibi ayẹyẹ igbade ogun ọdun ti Ọba AbdulRafiu Ajiboye, Oyelaran kinni, Oloro tiluu Oro ni gbogbo ọmọ ilu naa ti panupọ lati fi oye ọhun da AbdulRazaq lọla.

Awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn je ọmọ bibi ilu naa, ti wọn pe ara wọn ni Oro Descendants Union la gbọ pe wọn kede AbdulRazaq fun oye tuntun naa, ko to di pe Ọba Oyelaran gbe ade lee lori, ti wọn si tun fun un ni ilẹkẹ ati ọpa aṣẹ oye naa.

Nibẹ naa ni wọn tun ti yan iyawo Gomina AbdulRazaq, Aṣoju Olufọlakẹ AbdulRazaq gẹgẹ bi Yeye Akorede ilu Oro, pẹlu awọn alẹnulọrọ miran ti wọn tun fi j'oye latari ipa ti wọn n ko ninu eto idagbasoke ilu naa. 

Ayẹyẹ ọhun lo kun fun ọpọ awọn aṣofin agba ati kekere, awọn alẹnulọrọ ninu ijọba ati oṣelu, awọn Ọba at'awọn oloye, to fi mọ awọn araalu, nipinlẹ Kwara ati orileede Naijiria lapapọ.

Nibi eto ọhun ni wọn ti ṣeleri atilẹyin saa keji fun AbdulRazaq, ti wọn si akitiyan rẹ nipa idagbasoke wu awọn lori, paapaa bi wọn ṣe sọ pe ko si lara awọn adari to n ṣe oṣelu ẹlẹyamẹya.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI