Wọn lawọn ṣọọṣi ti n kọ owo naira atijọ s'awọn ọmọ ijọ lọrun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 30, 2023

Wọn lawọn ṣọọṣi ti n kọ owo naira atijọ s'awọn ọmọ ijọ lọrun


Pupọ awọn ile ijọsin kaakiri orileede yii ni wọn kede f'awọn ọmọ ijọ wọn pe wọn ko gbọdọ fi owo atijọ san owo ọrẹ ati idamẹwaa mọ, nitori t'awọn ko nii gba a.
 
Eyi lo ṣelẹ lẹyin ti banki agba orileede Naijiria, CBN ti kede pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun yii ni yoo gbe gbedeke ọjọ ti awọn eeyan yoo na owo atijọ naa gbẹyin, ti wọn yoo si bọ sori tuntun.
 
Ọpọ awọn eeyan lo lọ to sẹnu ọna banki lati gba owo, ṣugbọn ti wọn ko ri owo wọn gba.
 
Yatọ si awọn to lọ gba owo, awọn miran tun lọ to sile epo lati ra pẹtiroolu, eyi to di ọhọngogo.
 
Ni bayii, banki agba ti wa fi kun gbedeke ọjọ naa, ti wọn si ni ọjọ kẹwaa, oṣu keji lawọn eeyan yoo na owo naira atijọ naa mọ, eyi to fi lawọn fẹ ki owo tuntun naa kari gbogbo eeyan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI