Wọn tun ti ji gbajumọ olukọ to n tọmọ lọwọ l'Ọṣun gbe o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 26, 2023

Wọn tun ti ji gbajumọ olukọ to n tọmọ lọwọ l'Ọṣun gbe o


Ileeṣẹ eleto aabo-ara-ẹni-laabo-ilu ti a mọ si Sifu Difẹnsi, Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC), ẹka t'ipinlẹ Ọṣun ti f'idi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn kan ti ji olukọ kan, Arabinrin Ọlayinka Kayọde to n tọ ọmọ ikoko ati ọmọ naa gbe.
 
Ọlayinka, ẹni ti wọn sọ pe ile ẹkọ Union Baptist Church, to wa niluu Oṣogbo lo ti n ṣiṣẹ ni wọn ji oun ati ọmọ to n tọ lọwọ gbe lakoko to n lọ sile.
 
Wọn ni bi obinrin naa ṣe kuro ni ṣọọbu rẹ to ti n ta ọja ni nnkan bi aago mẹfa irọlẹ, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, to si n lọ sile ni awọn agbebọn ajinigbe naa tẹle lagbegbe Ọtaẹfun/Kobo.
 
Pasitọ ṣọọṣi ti obinrin naa n lọ, Pasitọ Sunday Adeoye nigba toun naa n f'idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe awọn ajinigbe naa ti pe ọkọ arabinrin naa lori foonu, wọn si n beere fun miliọnu marun-un naira, ki wọn to le fi oun atọmọ ọwọ rẹ silẹ.
 
Ninu ọrọ Pasitọ naa, o ni;
"Wọn sọ pe inu apo owo obinrin naa ni ka lọ san owo ọhun si
 
"A ti n rawọ ẹbẹ fun adura, ati iranlọwọ lati ọdọ awọn eeyan kaakiri, nitori pe a gbagbọ ninu Ọlọrun wi pe wọn maa fi Ọlayinka Tosin Kayọde ati ọmọ rẹ silẹ layọ ati alaafia, ti wọn si maa pada lọ ba awọn mọlẹbi wọn ati ijọ Ọlọrun laipẹ."
 
Kẹhinde Adeleke to jẹ agbẹnusọ f'awọn Sifu Difẹnsi nipinlẹ naa sọ pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati rii pe wọn gba obinrin naa ati ọmọ rẹ silẹ kuro lahamọ ajinigbe ti wọn wa laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI