O ga o! Wọn yinbọn pa alaga ẹgbẹ oṣelu APC danu, wọn tun ji awọn ọmọ ẹgbẹ naa marun-un lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 26, 2023

O ga o! Wọn yinbọn pa alaga ẹgbẹ oṣelu APC danu, wọn tun ji awọn ọmọ ẹgbẹ naa marun-un lọ


Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ni wọọdu Umuchoke to wa lagbegbe Okwe, ijọba ibilẹ Onuimo, ipinlẹ Imo la gbọ pe awọn agbebọnrin kan ti yinbọn pa danu.
 
Christian Ihim, ni wọn pe orukọ alaga ẹgbẹ oṣelu APC, ẹni ti wọn wọn sọ pe wọn yinbọn pa l'Ọjọru, Wẹsdiee, ọsẹ yii.
 
Yatọ Ihim, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Zako ti wọn yinbọn pa, a gbọ pe awọn agbebọn naa tun ji awọn oloye ẹgbẹ naa marun-un salọ.
 
A gbọ pe bawọn agbebọn naa ṣe ya wọ agbegbe yii, ṣe ni wọn dabọn bolẹ, eyi to mu ki gbogbo awọn to n gbe lagbegbe naa sa asala fun ẹmi ara wọn.
 
Siwaju sii la tun gbọ pe awọn agbebọn yii tun ya ni agbegbe kan to sunmọ ibi ti wọn ti ṣọṣẹ yii, iyẹn Okwelle, nibi ti wọn ti ji ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ APC to jẹ obinirin, Onyinyech Egenti gbe.
 The gunmen also invaded a neighbouring community Okwelle and kidnapped a female member of the APC Onyinyech Egenti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI