Alaṣẹ ati olusilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele ti sọ pe oludije sipo Aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar ni yoo jawe olubori ninu eto idibo to wọle fe yii.
Wolii Ayọdele lo sọrọ naa ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Oluwatosin Ọṣhọ gbe jade laaarọ oni, ọjọ Ẹti, Furaidee.
O ni ẹni to ba jawe olubori lẹkun Ariwa orileede Naijiria ni yoo di aarẹ tuntun.
Bakan naa lo sọ pe Atiku ko le ṣe ikọba ju saa kan ṣoṣo, iyẹn ọdun mẹrin lọ, nitori pe ileri Oluwa ni.
Wolii Ayọdele fi kun ọrọ rẹ pe Ọlọrun lo yan Atiku lati di aarẹ Naijiria, nitori pe o ni iṣẹ pataki lati ṣe fawọn araalu
Siwaju sii lo sọ pe Peter Obi, oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour ko le lọ sibikibi, nitori pe ko le ri ibo kankan lati ilẹ Hausa, to si ni ibi ti ibo pọ ju si niyẹn.
Wolii Ayọdele jẹ ko di mimọ pe Bọla Ahmẹd Tinubu yio ja fitafita lati ri ọwọ mu lẹkun Ariwa Naijiria, ṣugbọn Atiku yoo bori rẹ daadaa, ati pe awọn Ariwa ni yoo sọ Aarẹ tuntun.
"Mo ni iran lori eto idibo Aarẹ ọdun 2023 yii. Mi o sọ pe ki ẹnikẹni gba mi gbọ tabi ki wọn ma gba mi gbọ, ṣugbọn ọrọ yoo sọ ara rẹ.
"Nko tako ẹnikẹni. Peter Obi, Tinubu ati Atiku ni wọn dara, mo ti sọ ọ tẹlẹ ri wi pe imọtara wọn nikan ni wọn mọ, o yẹ ki wọn ti jọ parapọ, ṣugbọn nitori pe wọn ko ṣe bẹẹ, ẹnikan ṣoṣo naa ni yoo jawe olubori.
"Mo ri Atiku ati Tinubu ti wọn n jijakadi ni Ariwa orileede yii, nibi ti ibo pọ si julọ. Peter Obi, o jẹ ẹnikan to dara, ṣugbọn awọn Ariwa ko nii gba ọ laaye.
"Ilana eto idibo yoo bẹrẹ sii yi pada lati akoko yii titi di aarọ ọla. Tinubu ati Atiku ni wọn yoo maa pariwo rẹ. Wọn yoo si gbe Obi ṣegbẹ kan, idi ree to fi yẹ ki oju ti awọn gomina marun-un nni (G-5 governors).
"Ni igbẹyin gbogbo rẹ, awọn Ariwa yoo dibo wọn fun Atiku, eyi si ni yoo sọ ẹni ti yoo jawe olubori ninu eto idibo yii."
"Bi idibo yoo ba waye bayii, Atiku yoo jawe olubori nilẹ Ariwa, nitori pe iyalẹnu ni eto idibo yoo jẹ nibẹ. Gẹgẹ bi mo ṣe sọ ṣaaju, ibo Ariwa ni yoo sọ eni ti yoo jawe olubori, kii ṣe ri Iwọ-Oorun tabi Ila-Oorun."
No comments:
Post a Comment