Gbogbo ẹyin ti ẹ sọ pe mo gba ọkọ ọlọkọ ni oju maa ti laipẹ - Debbie Ṣhokọya yẹyẹ awọn to n sọrọ rẹ laida - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 24, 2023

Gbogbo ẹyin ti ẹ sọ pe mo gba ọkọ ọlọkọ ni oju maa ti laipẹ - Debbie Ṣhokọya yẹyẹ awọn to n sọrọ rẹ laida


Gbajugbaja oṣerebinrin nni, Deborah Shokọya, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Debbie Shokọya ti bu ẹnu atẹ lu gbogbo awọn to n sọrọ nipa baale ile kan to n ba jade bayii, to si ni oju yoo ti gbogbo wọn laipẹ.

Debbie lo sọrọ naa loju opo Insitagiraamu rẹ nigba to n gbe fọto idunnu rẹ kan sita, to si ni ẹnu oun yoo too gba ọpẹ, nigba ti gbogbo erongba oun ba pada ja si rere tan.
 
O ni ijọ Dafidi n bọ lẹsẹ oun laipẹ, eyi ti yoo jẹ ki gbogbo awọn ọta oun gba itiju nla.
 
Ninu ọrọ to kọ sibẹ, o ni “Mo maa jijo ọpẹ, awọn eeyan yoo si wo mi bi mo ṣe n jo gẹgẹ bii Dafidi.
 
Iyin yoo kun ẹnu emi ọmọ Ọlọrun titi di igbẹyin.
 
Ireoluwa Ama wamiri ni gbogbo ojumo aiye mi”.
 
Fawọn ti ko ba mọ, laipẹ yii ni wọn fẹsun kan Debbie Shokọya wi pe awọn ọkọ ọlọkọ lo n gba kaakiri, koda ti oniroyin kan ti wọn n pe ni Gistlover tun fẹsun kan an wi pe ọkunrin kan to n jẹ Lukman Ejalonibu ni obinrin naa n ba jade bayii.
 

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI