Awa ko ṣe iwadii lọ sile Tinubu o - EFCC pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 19, 2023

Awa ko ṣe iwadii lọ sile Tinubu o - EFCC pariwo sita


Ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọkumọ ati iwa jibiti lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ti pariwo sita wi pe ko si otitọ kankan ninu iroyin to n kaakiri ori ikanni ayelujara wi pe awọn ṣe iwadii obitibiti owo kan de ile oludije sipo Aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu.

Lonii, ọjọ Aiku, Sannde ni ajọ EFCC kede ọrọ naa, ti wọn si ni irọ to jinna si otitọ pọmbele ni.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ naa, Wilson Uwujaren fi si oju opo agbẹyẹfo, iyẹn Twitter wọn ni aago mẹta ku iṣẹju mẹfa (3:56pm), lọsan oni, lo ti sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba iroyin naa gbọ, nitori pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni.

EFCC sọ pe awọn ko ṣe iwadii kankan, bẹẹ si l'awọn ko ri owo to to irinwo biliọnu naira de ile Tinubu to wa ni Bourdilon, nitori pe awọn ko gba ibẹ kọja, depodepo wi pe awọn yoo ri owo to to bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI