Awọn oludije s'ipo aṣofin agba meji juwọ silẹ fun Gbenga Daniel, wọn ni aṣaaju rere t'awọn nigbagbọ ninu ẹ ni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 19, 2023

Awọn oludije s'ipo aṣofin agba meji juwọ silẹ fun Gbenga Daniel, wọn ni aṣaaju rere t'awọn nigbagbọ ninu ẹ ni


Bi idibo apapọ orileede Naijiria ṣe ku ọjọ mẹjọ pere, awọn oludije s'ipo aṣofin agba lẹkun Ila-oorun ipinlẹ Ogun lati inu ẹgbẹ oṣelu meji ọtọọtọ ni wọn ti lawọn ṣetan lati juwọ silẹ fun oludije lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Ọtunba Gbenga Daniel, nitori pe aṣaaju rere t'awọn nigbagbọ ninu ẹ ni.
 
Oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, AA, Dayọ Ogunjẹbẹ ati Arabinrin Funmilayọ Idris, toun jẹ oludije s'ipo naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party, ADP, ni wọn lawọn ko dije mọ, nitori gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ogun, Ọtunba Daniel, ẹni t'awọn eeyan tun mọ si OGD.
 
Awọn mejeeji yii ni wọn kede sita wi pe awọn ti juwọ silẹ, pẹlu ileri wi pe awọn yoo ko gbogbo ọmọ ẹyin wọn lati dibo fun OGD l'opin ọsẹ to n bọ lọna yii.
 
Nibi aṣekagba ipolongo ti OGD ṣe niluu Itoro, ijọba ibilẹ Ijẹbu-Ode ni wọn ti sọrọ naa jade.
 
Nigba ti awọn mejeeji n sọrọ lori idi pataki ti wọn fi lawọn ko dije mọ, wọn ni awọn ri OGD gẹgẹ bi aṣaaju rere to ṣee tẹle, ti awọn si mọ ipa to ko lakoko to wa n'ipo gomina ipinlẹ Ogun, idi ree ti wọn fi lawọn mọ ipa ti yoo ko, to ba lọ ṣoju gbogbo agbegbe Iwọ-Oorun ipinlẹ naa l'Abuja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI