Awọn agbaagba Babanloma ṣeleri ibo rẹpẹtẹ f'AbdulRazaq ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 23, 2023

Awọn agbaagba Babanloma ṣeleri ibo rẹpẹtẹ f'AbdulRazaq ni Kwara


Gbogbo awọn agbaagba ati alẹnulọrọ lagbegbe Babanloma to wa n'ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ipinlẹ Kwara ti lawọn ti pari eto lati dibo rẹpẹtẹ AbdulRahman AbdulRazaq lati pada s'ipo gomina lẹẹkeji.
 
Awọn agbaagba naa lo ṣeleri naa laipẹ yii, ti wọn si ni gbogbo awọn oludije s'ipo oṣelu labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lawọn yoo dibo fun rẹpẹtẹ.
 
Gbogbo awọn agbaagba ọhun labẹ aburada ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) Elders’ Forum niluu Share, iyẹn ni wọọdu kẹta ati wọọdu kẹrin ni wọn fidi rẹ mulẹ.

Nibi ipade ọhun ni wọn tun ti jẹ ko di mimọ pe ibo aarẹ ati ile igbimọ aṣofin lawọn yoo fi bẹrẹ, lati le jẹ ki awọn eeyan mọ pe APC lawọn ṣatilẹyin fun.
 
Nigba to n sọrọ, alakoso ẹgbẹ awọn agbaagba naa, Alagba Nicholas Agboọla, sọ pe ipa ti gomina naa ti ko, ni yoo jẹ kawọn dibo fun un lẹẹkeji, nitori pe awọon ti rii gẹgẹ bii angẹli fun ipinlẹ Kwara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI