INEC ko ṣetan fun eto idibo nipinlẹ Ogun - Alaga ẹgbẹ akoroyin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 23, 2023

INEC ko ṣetan fun eto idibo nipinlẹ Ogun - Alaga ẹgbẹ akoroyin


Alaga ẹgbẹ awọn akọroyin nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Ọlawale Ọlanrewaju ti sọ pe gbogbo igbesẹ ti ajọ eleto idibo nipinlẹ naa n gbe ko jọ bi ẹni pe wọn ti ṣetan fun eto idibo apapọ ọdun 2023.

Nibi ipade ti ẹgbẹ akọroyin ṣe ni ile ẹgbẹ wọn to wa ni Iwe-Irohin, Oke-Ilewo, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni alaga naa ti sọ pe ajọ eleto idibo ko ni adehun kankan pẹlu ẹgbẹ naa, eyi to sọ pe ko ṣẹlẹ ri.

Kọmureedi Ọlawale Ọlanrewaju sọ pe o ti le ni oṣu kan gbako ti awọn akọroyin ti fi orukọ silẹ loju opo ajọ INEC, eyi ti wọn fi fẹẹ mọ awọn ti yoo kopa gẹgẹ bi akọroyin kaakiri Naijiria.

O ni gbara ti iforukọsilẹ naa ti pari, ni awọn ko ti gbọ ohunkohun lati ọdọ INEC, koda to láwọn ti gbiyanju lati ba alaga ajọ INEC, Niyi Ijalaye sọrọ nipa ohun ti wọn ni fawọn akọroyin, ṣugbọn to ni pabo ni gbogbo rẹ ja si.

Alaga naa tẹsiwaju pe oun pẹlu awọn oloye ẹgbẹ ti lọ sọdọ ajọ INEC lati le mọ bi awọn eeyan wọn yoo ṣe rin láti ṣe ojúṣe wọn.

Bakan naa lo rọ ajọ INEC lati tete ṣe ojúṣe wọn ki asiko too lọ, nitori pe ipa ti akọroyin n ko lakoko idibo ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.

Siwaju sii lo rọ awọn akọroyin lati ṣe ojuṣe wọn lakoko idibo, ati pe ki wọn ma ṣe polongo ibo fun oloṣelu kankan, nitori pe asiko to gbẹgẹ ni akoko oṣelu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI