Awọn agbebọn yinbọon f'alaga ẹgbẹ oṣelu PDP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 14, 2023

Awọn agbebọn yinbọon f'alaga ẹgbẹ oṣelu PDP


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori awọn to yinbọn fun alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ni wọọdu Ogbaku, ijọba ibilẹ Mbaitoli, ipinlẹ Imo, sibẹ, kayeefi ni ikọlu ọhun ṣi n jẹ.
 
Nnkan bi aago mẹsan ku iṣẹju kan alẹ ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii ni ikọlu ọhun waye nile ẹ to wa ladugbo Umunomo Nsokpo, iyẹn lagbegbe Ogbaku.
 
A gbọ pe niṣe lawọn agbebọn naa fo fẹnsi ile rẹ wọle lakoko ti ko si nile, ti wọn si duro de e, to fi de, ko to di pe wọn yinbọn fun un.
 
Ọkan lara awọn ara agbegbe naa to ba awọn akọroyin sọrọ jẹ ko di mimọ pe bi alaga naa ṣe n wọnu ọgba ile ẹ, ni wọn kọluu.

Ẹni naa ni bi alaga ọhun ṣe ri wọn, lo ti sare pariwo sita, to si fẹ maa sa wọnu ile lọ, ko to di pe wọn yinbọn fun un lẹsẹ
 
L'oju ẹsẹ lo sọ pe awọn agbebọn naa tun ti fo fẹnsi, ti wọn si na papa bora.
 
Agbẹnusọ f'ẹgbẹ PDP nipinlẹ naa, Collins Opuruozor, ti jẹ ko di mimọ pe iwadii ti n lọ lọwọ, pẹlu igbagbọ wi pe ọwọ yoo tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹ buruku naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI