O ma ṣe o: Ọmọ ọdun mẹrinla ku sinu agbami okun [Fọto] - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 14, 2023

O ma ṣe o: Ọmọ ọdun mẹrinla ku sinu agbami okun [Fọto]


Ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹrinla kan la gbọ pe o ti ku sinu agbami okun nla lọjọ Aje, Mọnde, ana, ọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 2023 ti a wa yii.
 
Ashfa Ibrahim, ni wọn pe orukọ ọmọ to ku somi naa labule Danzaki, ijọba ibilẹ Gezawa, ipinlẹ Kano.
 
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ panapana nipinlẹ naa, Alaaji Saminu Abdullahi ṣe ṣalaye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, onii, o sọ pe o jẹ ẹdun ọkan wi pe ọmọ naa ti ku k'awọn too debẹ.
 
O ni ẹnikan to n jẹ Ibrahim Abdullahi lo sare pe awọn lori foonu, ti awọn si debẹ pẹlu irinṣẹ igbalode, ati awọn akọṣẹmọṣẹ omuwẹ, ti wọn si gbe e jade.
 
Bẹẹ lo sọ pe ọsibitu jẹnẹra ti Gezawa lawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe ọmọ naa ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
 
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ, wi pe awọn ti fa oku rẹ le olori abule naa, Muhammed Abdulkarim, lati sinku rẹ gẹgẹ bo ti tọ, ati bo ti yẹ.
 


 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI