Awọn meji to ra mọto tọkọ-tiyawo ti wọn dana sun l'Abẹokuta ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 15, 2023

Awọn meji to ra mọto tọkọ-tiyawo ti wọn dana sun l'Abẹokuta ti ha o


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti jẹ ko di mimọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn meji to ra mọto tọkọtaya ti wọn dana sun niluu Abẹokuta nirakura ti ha, wọn si ti wa lahamọ awọn.
 
Azeez Usman ati Owolaja Aanuoluwapọ lawọn mejeeji tọwọ tẹ lori ẹsun pe wọn ra mọto ti wọon jigbe nirakura, wọn si tun ṣa ta gẹgẹ bii mọto aloku.
 
Ẹgbẹrun lọna aadọjọ la gbọ pe wọn ra mọto naa ti owo rẹ ko din ni miliọnu mẹrin naira.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, FRank Mba ti paṣẹ pe ki wọn lọ foju wọn ba ile-ẹjọ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI