Awọn oni 'POS' to n gba owo aitọ lọwọ araalu yoo rugin oyin laipẹ - CBN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 14, 2023

Awọn oni 'POS' to n gba owo aitọ lọwọ araalu yoo rugin oyin laipẹ - CBN


Banki agba lorileede Naijiria, Central Bank of Nigeria (CBN) ti sọ pe awọn to n fi owo ṣowo, iyẹn POS kaakiri orileede Naijiria, ti wọn n gba owo aitọ lọwọ araalu ni yoo foju winna ofin laipẹ.
 
Gomina Godwin Emefiele lo sọ eyi di mimọ nibi ipade to ṣe pẹlu awọn kan laipẹ yii niluu Abuja.
 
Emefiele ni gbogbo awọn to n ṣe POS, ti wọn n gba kọja iye ti banki fi lelẹ lawọn yoo foju wọn winna ofin, ti wọn yoo si jiya ẹṣẹ wọn.
 
O ni akoko ipenija ree f'awọn ọmọ Naijiria, ko wa yẹ ki awọn kan maa lo anfaani rẹ lati fi f'iya jẹ araalu lọna aitọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI