Ẹ dakun, ẹ jẹ k'awọn araalu ri owo wọn gba - Gomina AbdulRazaq rọ awọn alakoso CBN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 9, 2023

Ẹ dakun, ẹ jẹ k'awọn araalu ri owo wọn gba - Gomina AbdulRazaq rọ awọn alakoso CBN


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti rawọ ẹbẹ s'awọn alakoso banki agba lorileede Naijiria, CBN lati ko owo naira tuntun jade sita, fun irọrun araalu.
 
AbdulRazaq lo rawọ ẹbẹ naa lakoko to n gba awọn alakoso banki CBN lalejo niluu Ilọrin, nibi to ti rawọ ẹbẹ pe ki wọn ko owo jade sita f'awọn eeyan lati rii na.

Nibi abẹwo naa ti ẹka CBN to n ri sọrọ awọn araalu, iyẹn CBN Consumer Protection Department, eyi ti Arabinrin Raṣhidat Jumọkẹ Monguno lewaju wọn ni AbdulRazaq tun ti sọ pe ki CBN ṣe agbeyẹwo ilana kikowo jade wọn.
 
O lawọn ọlọja, oniṣowo, onileeṣẹ, agbẹ ati bẹẹbẹẹlọ ni wọn nilo owo lati na, paapaa fun idagbasoke eto ọrọ aje wọn lasiko yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI