Ọwọngogo epo ati owo naira tuntun: Ijọba Kwara gbe iranwọ nla dide f'awọn araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 9, 2023

Ọwọngogo epo ati owo naira tuntun: Ijọba Kwara gbe iranwọ nla dide f'awọn araalu


Idunnu nla ni gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara wa lasiko yii, iyẹn lori bi ijọba ipinlẹ naa labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe bu ọwọ lu iranlọwọ f'awọn araalu naa.
 
A gbọ pe Gomina AbdulRazaq ti bu ọwọ lu owo iranwọ f'awọn araalu lati maa fi ṣowo, ati ounjẹ ti yoo jẹ ki igbe aye rọrun fun gbogbo wọn, gẹgẹ bi ẹlẹyinju aanu mẹkunnu.
 
Igbesẹ yii la gbọ pe o lọ nibamu pẹlu bi epo bẹntiroolu ati aisi owo niluu ṣe di goolu to ṣoro lati ri f'awọn araalu.

Lara awọn iranwọ t'ijọba bu ọwọ lu f'awọn araalu ni fifi owo ranṣẹ sinu aṣunwo owo araalu, bii opo, arugbo, oṣiṣẹfẹyinti, awakọ, oniṣowo, ọlọja, agbẹ atawọn to ku diẹ kaatoo fun.
 
Abẹ eto ti wọn pe ni Kwara State Social Investment Programme (KWASSIP) ni ijọba Kwara ti kede iranwọ naa, ti a si gbọ pe wọn yoo ṣe lai ṣe ojuṣaaju tabi fi ọrọ oṣelu sii.

Yatọ si eyi, a tun gbọ pe ijọba tun ti pese mọto ọfẹ ti yoo maa gbe awọn ọmọ ileewe lọ sileewe wọn, ti yoo si tun maa da wọn pada sile wọn lai san owo kankan.
 
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu keji ti a wa yii ni gbogbo eto ọhun yoo bẹrẹ ni pẹrẹu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI