Ẹ jẹ ka maa na owo atijọ lọ, tabi ki ẹ ko owo tuntun jade - Adeleke - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 16, 2023

Ẹ jẹ ka maa na owo atijọ lọ, tabi ki ẹ ko owo tuntun jade - Adeleke


Gomina Ademọla Adeleke t'ipinlẹ Ọṣun ti ṣe ikilọ nla fun gbogbo awọn banki patapata ti wọn n kọ owo naira atijọ, ti wọn ko si ko owo tuntun sita.
 
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ f'Adeleke, Ọlawale Rasheed gbe jade l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii, Adeleke kọminu lori wahala t'awọn araalu n koju lori owo tuntun ati ti atijọ naa, nipa ofin ati ilana ti banki apapọ orileede yii, Central Bank of Nigeria, CBN gbe kalẹ.
 
Nibẹ lo ti sọ pe oun ko le laju silẹ lati maa wo bawọn araalu ṣe n jiya lori owo wọn to wa ni banki,to si n rọ wọn lati ko owo sita f'awọn to nilo rẹ.

"Ẹdun ọkan lo n jẹ fun mi lati maa wo b'awọn araalu ṣe jiya lori owo wọn lasiko yii. Igbe aye ti wa da ohun to nira f'awọn eeyan. Gbogbo ẹka patapata ni wọn n la iṣoro ati idaamu ti ko ṣee fẹnu sọ kọja. Mo o pe gbogbo awọn alakoso banki patapata lati boju aanu wo awọn eeyan wa.

"Ẹni lati ko owo naira tuntun sita f'awọn eeyan, tabi ka tẹsiwaju lati maa na owo atijọ. Ẹ jẹ ka dekun titi awọn araalu, koda, lasiko ti wọn ko ṣẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI