Gomina araalu l'AbdulRazaq, a fi ka dibo fun lẹẹkeji - Etsu Patigi ṣeleri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 16, 2023

Gomina araalu l'AbdulRazaq, a fi ka dibo fun lẹẹkeji - Etsu Patigi ṣeleri


Etsu tiluu Patigi, Alaaji Ibrahim Umar, Bologi keji ti sọ pe gomina araalu ni gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq, ati pe o ti di dandan fun wọn lati dibo fun un lẹẹkeji.
 
O ni ọkan awọn araalu balẹ lori gomina wọn laaarin ọdun mẹta ati oṣu bii mẹjọ to ti wa n'ipo iṣakoso, eyi to ni awọn akanṣe iṣẹ to ti ṣe ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.
 
Etsu ni ọwọ ti AbdulRazaq n bọ fawọn ọba alaye ko kere, to si n fun wọn ni ọwọ to tọ, to si ṣe daadaa.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni Etsu Patigi sọrọ naa niluu Patigi, ijọba ibilẹ Patigi nibi ipolongo idibo ti gomina ati awọn oludije lẹgbẹ oṣelu APC ṣe lọ sibẹ.
 
Nibẹ lo ti sọ pe gomina to n farabalẹ gbọ ohun ti awọn araalu n sọ ni AbdulRazaq, to si lo ti di dandan lati dibo fun un lẹẹkeji, ko le tẹsiwaju ninu awọn akanṣe iṣẹ to n ṣe lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI