Ẹ ṣi fi owo ọrẹ ati idamẹwa silẹ lasiko yii - Wolii Jẹnẹsiisi sọ fawọn ọmọ ijọ rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 6, 2023

Ẹ ṣi fi owo ọrẹ ati idamẹwa silẹ lasiko yii - Wolii Jẹnẹsiisi sọ fawọn ọmọ ijọ rẹ


Gbajugbaja iranṣẹ Ọlọrun nni, Wolii Israel Ọladele Ogundipẹ, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Wolii Jẹnẹsiisi (Genesis) ti parọwa fun gbogbo awọn ọmọ ijọ rẹ lati dẹkun sisan owo ọrẹ ati idamẹwa wọn fun igba diẹ.

O ni gbogbo wahala ati rogbodiyan to n ṣẹlẹ lorileede Naijiria lasiko yii, to nnkan ti eeyan n ronu le lori, wọn ko si gbọdọ maa fi ara ni awọn eeyan nitori ẹsin.

Wolii Jẹnẹsiisi lo sọrọ yii lasiko to n waasu ninu ijọ rẹ to wa niluu Eko lọjọ Aiku, Sannde ana.

Ọpọ awọn ọmọ ijọ ni wọn patẹwọ, ti wọn si gbe oriyin fun Wolii Jẹnẹsiisi lori ipinnu to gbe kalẹ naa.

Fawọn ti ko ba mọ, owo ọrẹ ati idamẹwa l'awọn ẹlẹsin Kristẹni maa n da lakoko isin, yala ọjọ Aiku, Sannde ni, tabi awọn ọjọ miran.

Ojiṣẹ Ọlọrun naa gbe igbesẹ yii latari bi ko ṣe si owo naira tuntun, ati ọwọngogo epo rọbii to n ṣẹlẹ kaakiri Naijiria lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin.

Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe wọn yoo bẹrẹ sii gba owo ọrẹ ati idamẹwa pada lẹyin ti gbogbo rogbodiyan naa ba kasẹ nilẹ patapata.

O sọ pe awọn ijọ Ọlọrun naa mọ nnkan tawọn eeyan n fojoojumo koju lorileede Naijiria lasiko yii, ko si tun yẹ ki wọn da kun wahala fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI