Ile-ẹjọ agba paṣẹ pe k'awọn ọmọ Naijiria maa na owo atijọ lọ, lai ni gbedeke - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 9, 2023

Ile-ẹjọ agba paṣẹ pe k'awọn ọmọ Naijiria maa na owo atijọ lọ, lai ni gbedeke


Ile ẹjọ agba
(Supreme Court) orileede Naijiria ti paṣẹ wi pe ki awọn ọmọ orileede yii ṣi maa na owo atijọ t'awọn eeyan n na tẹlẹ lọ, lai ni gbedeke ọjọ ti yoo kasẹ nilẹ.
 
Oni, Ọjọru, Wẹsidee ni ile ẹjọ naa paṣẹ pe gbedeke ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun ti a wa yii ko nii ṣiṣẹ mọ, nitori pe ilana ti wọn fi gbe e kalẹ ko ba ofin mu.
 
Igbimọ ẹlẹnimeje ti Onidajọ John Okoro lewaju rẹ lo gbe idajọ naa kalẹ, eyi ti ipinlẹ mẹta ọtọọtọ, Kaduna, Kogi ati Zamfara pe lati tako banki agba orileede yii.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun ti a wa yii ni Gomina Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele sọ pe awọn araalu yoo na owo atijọ gbẹyin, eyii lo mu k'awọn ipinlẹ mẹta gbe e lọ sile ẹjọ wi pe ko le ṣee ṣe.
 
Igbesẹ yii la gbọ pe wọn fẹẹ fi dabaru eto idibo ọdun 2023, to mu ki Gomina Nasir El-Rufai ti ipinlẹ Kaduna, Gomina Yahaya Bello ti ipinlẹ Kogi ati Gomina Bello Matawalle  t'ipinlẹ Zamfara gba ile ẹjọ lọ.
 
Ile ẹjọ naa wa paṣẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Banki CBN, gomina rẹ, Godwin Emefiele ati awọn banki mẹtadinlọgbọn to wa lorileede yii ko gbọdọ dawọ nina owo atijọ duro
 
Bẹẹ lo tun sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹẹdogun, oṣu keji, ọdun ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI