Ẹwọn ọgbọn ọdun ni R. Kelly n ṣe lọwọ, ni wọn ba tun da ẹwọn ogun ọdun miran fun-un - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 24, 2023

Ẹwọn ọgbọn ọdun ni R. Kelly n ṣe lọwọ, ni wọn ba tun da ẹwọn ogun ọdun miran fun-un


O ti wa a f'oju han gbangba bayii pe gbajugbaja onkọrin agbaye nni, Robert Kelly, ẹni t'ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si R. Kelly ko le bọ ninu ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an, pẹlu bo tun ṣe gba idajọ ẹbi tuntun.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee ana ni ile ẹjọ Chicago ju Kelly, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta s'ẹwọn ogun ọdun, lori ẹsun wi pe o n fi fọnran ibalopọ han ọmọdebinrin kan ti ọjọ ori rẹ ko tii pe ọdun mejidinlogun.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọdun 2021 ni wọn ti kọkọ ju Kelly sẹwọn ọgbọn ọdun lori ẹsun ifipanilopọ nile ẹjọ New York, to si ti ṣe ọdun kan ninu ọdun naa.
 
Nigba to n gba idajọ naa kalẹ, Onidajọ ilẹ Amẹrika naa, Onidajọ Harry D. Leinenweber sọ pe Kelly yoo ṣe ẹwọn naa lera wọn lẹẹkan naa, tabi ko ṣee lọtọọtọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI