Dapọ Abiọdun f'itan tuntun balẹ l'Ogun: Ọkọ baluu akẹru akọkọ balẹ n'Iliṣan Rẹmọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 24, 2023

Dapọ Abiọdun f'itan tuntun balẹ l'Ogun: Ọkọ baluu akẹru akọkọ balẹ n'Iliṣan Rẹmọ


Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun 2023 ni Gomina Dapọ Abiọdun fi itan tuntun balẹ n'ipinlẹ Ogun pẹlu bi ọkọ baluu akẹru ti a mọ si Cargo ṣe balẹ siluu Ipẹru Iliṣan, ijọba ibilẹ Ikẹnnẹ.
 
Papakọ ofurufu ti Gateway Agro-Cargo Airport ni ọkọ baluu naa balẹ si, lati fi ṣe idanwo bi iṣẹ yoo ṣe bẹrẹ lẹkunrẹrẹ nigba ti iṣẹ ba tubọ pari patapata.
 
Lara awọn to wa nibi ayẹyẹ ifilọlẹ papakọ ofurufu akẹru naa ni; Awọn gomina tẹlẹri nipinlẹ Ogun bii Oloye Oluṣẹgun Ọṣoba, Ọtunba Gbenga Daniel; Akarigbo tilẹ Rẹmọ; Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo; minisita fọrọ ọkọ ofurufu, Sẹnetọ Hadi Abubakar Sirika ati awọn miran.
 
Nigba to n sọrọ, Gomina Dapọ Abiọdun jẹ ko di mimọ pe ala rere ti gomina tẹlẹri, Ọtunba Gbenga Daniel ti ni tipẹ lakoko to wa lori iṣakoso lo wa si imuṣẹ.

O ni agbegbe ti papakọ ofurufu naa wa yoo wulọ fun idagbasoke ati ilọsiwaju ilẹ Rẹmọ, ati pe yoo tun jẹ irọrun fun gbogbo awọn olokoowo kaakiri orileede Naijiria.
 
Abiọdun ni awọn to wa ni ẹkun Ariwa ati Ila Oorun orileede yii yoo ṣamulo papakọ ofurufu ọhun nitori pe oju ọna lo wa fun wọn.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI