Niṣe lọrọ naa dabi ẹfun ati eedi lọjọ Ẹti, Fraidee to kọja yii nigba ti eeyan mẹta ọtọọtọ ko sinu kọnga, ti wọn si gbabẹ gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra loju ẹsẹ.
Nnkan bi aago mẹsan aarọ niṣẹlẹ ọhun waye lagbegbe Ojoro to wa ni Owode Ẹdẹ, ijọba ibilẹ Ẹdẹ, ipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun ti a wa yii.
Adebayọ Oluwaṣina, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ti wọn pe ni pasitọ; Lateef Adediran, ẹni ọdun mejilelogun ati ẹgbọn rẹ, Waliu Adediran toun jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ni iroyin fi to wa leti pe wọn ku sinu kọnga, lakoko ti wọn n gbiyanju lati yọ ifami ti wọn n lo lati fi pọn omi, eyi to jabọ sinu kọnga.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe iṣẹ birikila ni Waliu ati Lateef n ṣe, ti Pasitọ Shina si gba wọn lati ba oun ṣiṣẹ ile to n kọ lọwọ.
Bi wọn ṣe debẹ laarọ ọjọ naa la gbọ pe Lateef lọ pọn omi, ti ifami naa si jabọ sinu kọnga ti wọn ko tii pari iṣẹ ninu ẹ. Wọn ni bi ifami yii ṣe jabọ ni Lateef ti ko sinu kọnga naa pẹlu erongba lati yọ ifami ọhun.
Alọ rẹ ni wọn ri, wọn ko rii ko jade mọ, eyi lo mu ki ẹgbọn rẹ, Waliu naa ko sibẹ lati yọ ọ, toun naa ko si tun pada jade.
Si iyalẹnu, wọn ni Pasitọ Ṣhina naa tun ko sinu ẹ lati doola ẹmi awọn mejeeji yii, ti wọn si loun naa ko tun le jade mọ.
Eyi lo jẹ iyalẹnu nla f'ọpọ awọn ara agbegbe yii, ti wọn fi sare ranṣẹ s'awọn oṣiṣẹ panapana n'ipinlẹ naa fun iranlọwọ.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ panapana, Ibrahim Adekunle to f'idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe o ṣeni laanu wi pe awọn mẹtẹẹta ti ku sinu kọnga naa lasiko t'awọn yoo fi debẹ, nitori pe oku wọn lawọn gbe jade.
O wa fi kun ọrọ rẹ pe awọn ọlọpaa ẹkun A to wa ni Ẹdẹ lo pada gbe oku awọn mẹtẹẹta lọ si mọṣuari, ko to di pe wọn fa awọn oku naa f'awọn mọlẹbi wọn.
No comments:
Post a Comment