Nitori gbese owo gbọmulelanta, iyaale ile dana sun ara rẹ mọ inu ile onile l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 19, 2023

Nitori gbese owo gbọmulelanta, iyaale ile dana sun ara rẹ mọ inu ile onile l'Abẹokuta


Kayeefi nla ni iṣẹlẹ ọhun jẹ patapata fun gbogbo awọn araalu Abẹokuta ati agbegbe ẹ, nigba ti iroyin jade sita wi pe iyaale ile kan ti wọn n pe ni Mama Dada deedee dana sun ara rẹ, to gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Oke-Keesi, to wa ni Itoko niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni iṣẹlẹ ọhun ti waye ni nnkan bi aago meji ọsan ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide to kọja yii.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni owo ele ti wọn n pe ni gbọmilelanta ni Mama Dada jẹ, eyi ti asiko to yẹ ko da owo naa pada si ti kọja, ṣugbọn ti awọn to ya owo lọwọ si n daamu ẹ lati tete san an.
 

A gbọ pe Mama Dada ko ba ti san owo naa, ṣugbọn gbogbo rogbodiyan airi owo gba ni banki ati ọwọngogo epo rọbii to n ṣẹlẹ kaakiri Naijiria, to mu ki ọpọ iṣẹ ati okoowo dẹnukọlẹ, lo fa a ti obinrin naa fi tete ṣe bi akikanju, nitori itiju.

Ẹgbẹrun lọna aadọrin (70,000) naira ni wọn sọ pe Mama Dada ya lọwọ ileeṣẹ to n ya awọn eeyan lowo ele naa lati fi ṣowo, ṣugbọn ti ko tete ri da pada nitori rogbodiyan to wa nita lakoko yii.
 
Pupọ awọn to sunmọ Mama Dada la gbọ pe owo gbese to jẹ naa ko ṣẹyin wọn, ti wọn si lojoojumọ lo fi n pariwo rẹ, to si n wa ọna bi yoo ti rii san.


Nigba ti iṣẹlẹ ọhun maa waye, wọn ni Mama Dada ran abigbẹyin rẹ ni epo bẹntiroolu. Ko si pẹ ti ọmọ naa lọ, ni wọn sọ pe obinrin yii da bẹntiroolu si ara rẹ, to si tun da a si gbogbo inu yara ile to ya gbe, ko to di pe o ṣana sira rẹ.

Alagba Babawale to jẹ akọwe agbegbe naa sọ pe niṣe ni Mama Dada fi iṣẹ ran ọmọ rẹ yii tan an jade, ki wọn ma ba a ku papọ, tabi ọmọ naa ma ba a jẹ idiwọ fun un.
 
Awọn ọlọpaa ni iroyin fi to wa leti pe wọn pada gbe oku obinrin naa lọ si mọṣuari ọsibitu jẹnẹra to wa ni Ijaye niluu Abẹokuta.
 
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, a ko tii ri alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ba sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI