Gbogbo awọn ti ko gba owo naira atijọ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ bi ọwọ ba tẹ wọn - Gomina Abiọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 15, 2023

Gbogbo awọn ti ko gba owo naira atijọ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ bi ọwọ ba tẹ wọn - Gomina Abiọdun


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti sọrọ, o tun fi ọwọ sọya wi pe gbogbo awọn ti wọn ko gba owo naira atijọ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ bi ọwọ palaba wọn ba segi.

Dapọ Abiọdun lo sọ eyi di mimọ niluu Abẹokuta ipinlẹ Ogun laipẹ yii, to si ni ile ifowopamọ, awọn olokoowo to ba kọ lati gba owo atijọ loun yoo tu ileeṣẹ wọn pa.

Bakan naa lo tun sọ pe yatọ si pe oun yoo ti ileeṣẹ wọn pa, oun yoo tun ni k'awọn agbofinro mu wọn, ki wọn si foju wọn winna ofin.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Kunle Ṣomọrin fi sita lonii, Ọjọru, Wẹsidee, o sọ pe awọn owo bii ẹgbẹrun kan naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati igba naira ti a n na tẹlẹ ṣi jẹ owo gidi ti a n na, ko si tii kasẹ nilẹ 

O ni iea ọdaju ti ko ba ofin mu l'awọn eeyan n hu lasiko ipenija yii, ti wọn ko si gbọdọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mu.

Bẹẹ lo sọ pe ẹnikẹni ti wọn ba ri, wi pe ko ba owo naa tete, ki wọn tete pe awọn nọmba ẹrọ ibanisọrọ meji yii lati fi to ijọba leti. Awọn nọmba naa ni; 09099611266 ati 08103341344.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI