Ile ẹjọ agba paṣẹ pe k'awọn ọmọ Naijiria tẹsiwaju lati maa na awọn owo tẹlẹ lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 15, 2023

Ile ẹjọ agba paṣẹ pe k'awọn ọmọ Naijiria tẹsiwaju lati maa na awọn owo tẹlẹ lọ


Ile ẹjọ agba orile-ede Naijiria, Supreme Court ti paṣẹ wi pe awọn ọmọ Naijiria lẹtọọ lati maa na awọn owo ti a n na tẹlẹ lọ, lai ni idaduro.

Onii, Ọjọru, Wẹsidee ni ile ẹjọ agba naa gbe idajọ yii kalẹ, wi pe k'awọn araalu tẹsiwaju lati maa na awọn owo naa lọ, titi di ọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun 2023 ti a wa yii.

Bẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni ile ẹjọ ti kọkọ paṣẹ pe oun wọgile ọrọ ti banki apapọ Naijiria, CBN sọ tẹlẹ wi pe ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun yii ni owo atijọ ko nii wulo mọ.

Ṣaaju akoko yii ni gomina ile ifowopamọ apapọ orileede Naijiria, Godwin Emefiele ti sọ pe ọjọ kẹwaa, oṣu keji ti a wa yii ni awọn ọmọ Naijiria ko ni lanfaani lati maa na awọn owo tẹlẹ naa mọ.

Ipinlẹ mẹta ọtọọtọ ni wọn gbe banki apapọ Naijiria, CBN, ijọba apapọ lọ sile ẹjọ lati tako ọrọ wi pe owo naira atijo yoo kasẹ nilẹ.

Awọn ipinlẹ naa ni; Kaduna, Kogi ati Zamfara.

Nigba to n sọrọ, agbẹjọro awọn ipinlẹ wọnyi, Abdulhakeem Mustapha (SAN) sọ pe ìjọba Naijiria kọ jalẹ lati tẹle ofin, paapaa aṣẹ ile ẹjọ.

Onidajọ John Okoro yo lewaju igbimọ onidajọ naa sọ pe ko tunọ lọ pe ẹjọ naa lẹkunrẹrẹ, ko si fi awọn ẹsun rẹ sibẹ.

Siwaju sii lo sọ pe ẹjọ naa ṣi n tẹsiwaju lọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI