Gomina Abiọdun ṣabẹwo si ọkunrin ti wọn yinbọn fun l'Abẹokuta, o gbe gbogbo bukata itọju rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 9, 2023

Gomina Abiọdun ṣabẹwo si ọkunrin ti wọn yinbọn fun l'Abẹokuta, o gbe gbogbo bukata itọju rẹ


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti ṣabẹwo ẹdun ọkan si baale ile kan ti ibọn ṣeeṣi ba lagbegbe Ṣapọn si Agọ-Oko niluu Abẹokuta, ipinlẹ naa l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
 
Abiọdun lo ṣabẹwo naa l'Ọjọru, Wẹsidee, ana si ọsibitu FMC ti ọkunrin naa, Gabriel Michael ti n gba itọju, to si jẹ ko di mimọ pe igbesẹ ti n lọ lati rii pe owo naira to n da wahala silẹ d'ohun igbagbe laipẹ.
 
Gomina Abiọdun to kọwọ rin pẹlu Kọmiṣanna fọrọ eto ilera, Dokita Tomi Coker; akọwe iroyin gomina, Kunle Ṣomọrin; amugbalẹgbẹ gomina lori ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya, Ọnarebu Olujimi Desmond; at'awọn miran.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun ni wahala ati rogbodiyan naa bẹ silẹ niluu Abẹokuta, nibi ti awọn tọọgi ti bẹrẹ sii ba dukia ile ifowopamọ kaakiri jẹ, ti wọn tun dana s'oju ona kaakiri.
 
Gomina Abiọdun sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ foun, nitori pe gbogbo igbesẹ loun n wa lati rii pe banki agba orileede yii ko owo tuntun sita f'awọn araalu lati ri na, ki awọn eeyan si le ri owo gba pẹlu irọrun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI