Nnkan ko gbọdọ ṣẹlẹ si eto idibo ọdun 2023 o - Ọbasanjọ ṣe ikilọ nla fun ijọba Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 9, 2023

Nnkan ko gbọdọ ṣẹlẹ si eto idibo ọdun 2023 o - Ọbasanjọ ṣe ikilọ nla fun ijọba Naijiria


Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti ṣe ikilọ nla fun ijọba orileede yii labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari wi pe nnkan ko gbọdọ ṣẹlẹ si eto idibo ọdun 2023 to n bọ lọna lọjọ karundinlọbọn, oṣu keji ati ọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun 2023.

Ọbasanjọ lo sọrọ naa  pẹlu ifoya wi pe o ṣee ṣe ki wọn sun eto idibo naa siwaju, pẹlu bi nnkan ṣe n lọ lasiko yii lorileede Naijiria lori ọrọ ọwọngogo epo bẹntiroolu ati aisi owo naira tuntun f'awọn araalu lati na.
 
Aarẹ tẹlẹri naa lo sọrọ yii lakoko ti awọn alakoso ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) ṣabẹwo sii bi ipalẹmọ eto idibo ṣe ti n sunmọ etile.
 
Inu ọgba ile ikawe aarẹ, iyẹn Olusegun Obasanjo Presidential Library (OOPL), to wa niluu Abẹokuta, ni ipade ọhun ti waye.
 
Awọn alaṣẹ naa ni alaga igbimọ apaṣẹ wọn, Ọmọwe Mani Ibrahim Ahmẹd; alaga lapapọ ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Ralph Nwosu ati oludije s'ipo aarẹ tẹlẹri lẹgbẹ naa, Chukwuka Monye lewaju wọn.
 
Nibẹ ni Ọbasanjọ ti sọ pe asiko ti awọn araalu fẹẹ mọ bi nnkan ṣe n lọ ree, to si gbawọn lamọran pe ki wọn mu ọrọ eto idibo lokukudun, ki wọn si ṣee bi awọn orileede to ti dagbasoke ṣe n ṣe e.
 
Balogun Owu sọ pe idibo Naijiria ni gbogbo agbaye n wo bayii, nitori pe wọn n fẹ lati mọ ibi to fẹẹ ja si.

“Asiko ti awọn eeyan n fẹ lati mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ la wa yii, ni nnkan bi ọsẹ mẹta si asiko yii, a maa lọ dibo; mo ni ireti wi pe nnkan ko ṣẹlẹ lodi si idibo. Ni ọsẹ mẹta si asiko yii, a maa yan adari ti yoo tukọ Naijiria fun ọdun mẹrin, ninu oṣu karun-un.

“Mo ti lọ si orileede Togo, Ghana ati Côte d’Ivoire lati ibẹrẹ ọsẹ yii; ohun to n jẹ wọn logun bayii ni bi nnkan ṣe n ṣẹlẹ lorileede Naijiria."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI