Ijẹbu-Igbo ni baba arugbo yii ti kuro, ilu Ikorodu ni wọn lo n lọ, ṣugbọn ti wọn ko rii mọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 2, 2023

Ijẹbu-Igbo ni baba arugbo yii ti kuro, ilu Ikorodu ni wọn lo n lọ, ṣugbọn ti wọn ko rii mọ


Titus Taiwo Ọṣhibajo, ni wọn pe orukọ baba agbalagba ti ẹ n wo yii, ẹni ọdun mọkandinlaadọrin [69] si ni wọn pe e pẹlu.
 
Ilu Ijẹbu-Igbo ni wọn lo ti kuro lati oṣu kẹrin, ọdun 2022, ti wọn si lo dagbere ilu Ikorodu, nipinlẹ Eko.
 
Latigba to ti lọ ni iroyin fi to wa leti pe wọn ko gburo rẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

A gbọ pe wọn ti fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, bẹẹ si ni wọn pariwo rẹ kaakiri, ṣugbọn ti gbogbo igbesẹ ti wọn n gbe lati rii ṣi n ja si pabo.
 
Ẹrọ ibanisọrọ 08054688787 tabi 09043764739 ni ki ẹ pe bi ẹ ba kofiri baba yii, tabi ki ẹ si fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI