Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, bí ó pẹ́ títí tí akólòlò ti ń pe báábààbáá, yóò padà pe baba. Ọjọ́ tí a bí ọmọ kọ́ ní ń rìn. Lẹ́yìn òkùnkùn biribiri, ìmọ́lẹ̀ yóò tàn. Ìyẹn ló yẹ kí a fi gbìyànjú gan-an láti mú ọkàn wa ṣinṣin lórí ọ̀nà tí ìṣòro Nàìjíríà yóò gbà yanjú.
Bí a bá wo ìṣòro Nàìjíríà yìí, a óò rí i pé kì í ṣe àná ló bẹ̀rẹ̀, ọ̀sẹ̀ tó kọjá kọ́ ni a bẹ̀rẹ̀ sí ní í kojú ìṣòro ní Nàìjíríà, kì í ṣe oṣù tó kọjá ní Jánúárì ọdún 2023 yìí, bẹ́ẹ̀ náà sì ni pé, kì í ṣe ọdún 2022 tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ parí rẹ̀ yìí ni ìṣòro Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀.
Ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí àwọn Òyìnbó Gẹ̀ẹ́sì Amúnisìn wọ ilẹ̀ Adúláwọ̀, tí wọ́n sì wá jẹ gàba lórí wa. Bí èyí bá yé wa kọjá ibi tí mo mú ẹnu bà yìí lọ, ẹ ó rí i pé, ọ̀nà àbáyọ wà sí ìṣòro wa, àwa ni a kò tíì ṣe tán láti tọ ìlànà náà.
Yorùbá ní, iṣu atẹnumọ́rọ̀ kì í jóná. Bí a bá ní sùúrù, tí a sì tún gbìyànjú láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run Ọba lórí ìṣòro wa, dandan ni kí a borí ìṣòro wa yìí. Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, a kọ́kọ́ gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ pé:
1.) Ọlọ́run Ọba wà.
2.) Ọlọ́run Ọba ló dá wa.
3.) Ọlọ́run Ọba lè tán gbogbo ìṣòro.
Lẹ́yìn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ ní i lọ́kàn pé gbogbo ìṣòro tí ń kojú Nàìjíríà ti tán. Ìdí ni pé, a gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù, kí á sì máa gbàdúrà sí Ọlọ́run Ọba. Mo ṣe àkíyèsí pé, èròǹgbà ọmọ Nàìjíríà pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lórí ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìṣòro tó ń kojú Orílẹ̀-èdè yìí. Lára àwọn èròǹgbà náà ni pé:
1.) kí àtúntò dé bá ìgbékalẹ̀ ètò Ìjọba Nàìjíríà;
2.) kí àyípadà dé bá ìwé òfin Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà;
3.) kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ó dá dúró nípa pípín kúrò nínú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà;
4.) kí ìdìbò oṣù Fẹ́búárì ọdún 2023 yìí fi ààyè gba ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà mẹ́ta tí Olùdíje du ipò Ààrẹ Orílẹ̀-èdè yìí ti jáde wá;
5.) Yorùbá ló kàn láti jẹ Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà;
6.) Ìgbò ló yẹ kó jẹ Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nítorí pé, wọn kò tíì jẹ Ààrẹ rí; àti pé,
7.) ó wu àwọn ẹ̀yà Ìlà-Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà láti tún bọ́ sípò Ààrẹ, bí Muhammadu Buhari bá kúrò níbẹ̀.
Èwo ló kan Ọlọ́run nínú gbogbo àwọn èròǹgbà méjèèje wọ̀nyí? Ọba tó máa ń ṣe èyí tó wù ú ni Ọlọ́run oo. Bí ó bá wu Ọlọ́run, Ó lè pa gbogbo èròǹgbà méjèèje náà rẹ́, kí ó jẹ́ ibòmíràn ni yóò gbà yọ sí wa. Ohun tí mo mọ̀ dájú ni pé, bí a bá pa ẹnu pọ̀, tí a ń bẹ Ẹ́ dáadáa, yóò sọ ìgbé ayé wa dẹ̀rọ̀ ní Nàìjíríà.
ÀKÍYÈSÍ PÀTÀKÌ:
Mo mọ̀ pé, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ wa ni yóò máa retí pé, ó yẹ kí n sọ ọ̀nà àbáyọ tí mo mú ẹnu bà lókè pé ó ti wà nílẹ̀, ṣùgbọ́n, a kò tọ̀ ọ́. Lóòótọ́ ni, ṣùgbọ́n, ọ̀nà àbáyọ náà kọ́ ló dára jù lọ, bí kò ṣe sùúrù àti àdúrà wa ni yóò tọ́ wa sọ́nà lórí ọ̀nà àbáyọ tí mo gbà lérò náà. Ẹ jẹ́ kí n wá sọ ọ̀nà àbáyọ náà ní ṣókí báyìí, tí n ó padà máa ṣàlàyé fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lọ́la lágbára Ọlọ́run Ọba Aláṣẹ.
Ọ̀NÀ ÀBÁYỌ SÍ ÌṢÒRO NÀÌJÍRÍÀ KÒ JU ẸYỌ KAN ṢOṢO LỌ:
1.) Kọ́kọ́rọ́ kan ṣoṣo tó ń ba ẹyín ajá Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ni ipò ẹrú àwọn Aláwọ̀ funfun tí Nàìjíríà wà, tí àwọn Adarí Orílẹ̀-èdè wa náà kò sì múra tán láti mú wa kúrò ní ipò ẹrú náà. Ọjọ́ tí ìfẹnukò bá wáyé láàrin àwọn Adarí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pé:
(i.) kí Nàìjíríà ja ìjàgbara kúrò lọ́wọ́ àwọn Orílẹ̀-èdè àgbáyé tí wọ́n pinnu láti máa ba ètò ọrọ̀-ajé wa jẹ́;
(ii.) kí àwọn Adarí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbìyànjú láti máa fi ikùn lu ikùn pẹ̀lú àwọn mẹ̀kúnnù lórí ọ̀rọ̀ ìṣèlú;
(iii.) kí Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe àwárí àwọn ọlọ́pọlọ pípé àti olóòótọ́ láàrin àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà;
(iv.) kí Ìjọba Àpapọ̀ máa ṣe àbẹ̀wò sí iṣẹ́ àkànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́gboyè àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yunifásítì, Kọ́lẹ́ẹ̀jì àti Ilé-Ẹ̀kọ́ Gbogbonìṣe láti mọ àbá àti ìmọ̀ràn àwọn Ọ̀dọ́ lórí àṣeyọrí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà;
(v.) kí Ìjọba Àpapọ̀ máa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá peregedé nínú ètò-ẹ̀kọ́ wọn ní ẹ̀bùn, ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́, ìwúrí, kóríyá, oríyìn àti ìdálọ́lá, kí wọ́n sì máa gbà wọ́n sí iṣẹ́ kí wọ́n tó sá kúrò ní Nàìjíríà.
ÌRÍRÍ MI LÓRÍ ÀWỌN ÌṢÒRO ÀTI Ọ̀NÀ ÀBÁYỌ WỌ̀NYÍ:
Mo nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀-Èdè Yorùbá gan-an, tí mo sì ṣe akitiyan láti mú èròǹgbà mi ṣẹ lórí rẹ̀. Èròǹgbà mi náà ni pé, n óò kọ́ ẹ̀kọ́ nípa èdè Yorùbá náà ní kíkún, bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ. Mo mú èròǹgbà náà ṣẹ nípa kíkọ́:
1.) Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀-Èdè Yorùbá ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni Àgbà TASUED
2.) Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀-Èdè Yorùbá lórí Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀ Àkọ́kọ́ (B. A.) ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ifẹ̀
3.) Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀-Èdè Yorùbá ní Ilé-Ẹ̀kọ́ lórí Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀ Kejì (M. A.) ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ifẹ̀
4.) Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀-Èdè Yorùbá ní Ilé-Ẹ̀kọ́ lórí Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀ Àgbà (PhD) ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ifẹ̀ tí n óò parí láìpẹ́.
Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀ Àkọ́kọ́ (B. A.) nínú èdè Yorùbá ní ọdún 2014 ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ifẹ̀, èmi ni mo peregedé jù lọ nínú gbogbo àwa tí a jọ kẹ́kọ̀ọ́ gboyè náà. Bẹ́ẹ̀ náà ni a rí onírúurú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ mi, tí àwọn náà peregedé ní Ẹ̀ka-Ẹ̀kọ́ tiwọn náà.
Ohun tí ó yà wá lẹ́nu ni pé, Ìjọba Àpapọ̀ kọ̀ láti ṣe kóríyá fún gbogbo wa. Èyí kọ́kọ́ bu omi sí ọkàn mi, tí n kò fẹ́ ka ìwé mọ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n George Olúṣọlá Ajíbádé tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Olùkọ́ mi ni ó gbà mí nímọ̀ràn láti padà sí ẹnu ẹ̀kọ́ mi, kí n gba oyè Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀ Kejì (M. A.),ní èyí tí n kò sì lè kọ ọ̀rọ̀ sí Ọ̀jọ̀gbọ́n náà lẹ́nu.
Inú mi kì í dùn, bí mo bá ń wo ìhà tí àwọn Adarí Nàìjíríà kọ sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti ètò-ẹ̀kọ́ Nàìjíríà lápapọ̀. Wọn kò fura pé, ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà gan-an ni orísun ìṣòro Nàìjíríà. Bí wọ́n bá mú ti àwọn Ọ̀dọ́ rò nípa ètò-ẹ̀kọ́ wọn, ìṣòro Nàìjíríà yóò dé òpin.
Ẹ ṣeun oo.
Láìpẹ́, Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò tùbà tùṣẹ oo. Àmí.
... mo dákẹ́ díẹ̀ ná...
...mo sì fi ìyókù síkùn bí àwọn àgbààgbà...
Mo júbà oo
Ìbà Ọlọ́run Èdùmàrè
Ìbà Kábíèsí Ọlọ́tà Odò
Ìbà Ọkùnrin
Ìbà Obìnrin
Ìbà Ọmọdé
Ìbà ẹ̀yin àgbààgbà
Ẹ jẹ́ kó yẹ mí oo.
©
ÌȘỌ̀LÁ Sauban Àlàdé Orí-Àrán lèmi ń jẹ́
Ẹ̀ṣọ́ Ọmọ Ọlọ́tà Odò
👏🙇♂️👏
No comments:
Post a Comment