Bí ètò ìdìbò Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ń kù fẹ́ẹ́rẹ́ láti yan àwọn Adarí Orílẹ̀-èdè titun nílẹ̀ yìí, àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ kí a gbé láti borí àwọn ìṣòro tí ń kojú wa ní Nàìjíríà kò pọ̀.
Ẹ jẹ́ kí a múra tán láti ṣe ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yìí. Yorùbá ní, àìsí níbẹ̀ ni àìbá wọn dá sí i. Bí a bá ń gbọ́ gbé-e-gbè-è-gbé-e, tí a kò bá wọn gbé, wọ́n lè gbé ohun ìjàǹbá sí ẹ̀yìnkùlé wa.
Bí a kò bá fẹ́ kí àwọn Òṣèlú Nàìjíríà jẹ wá mọ́ ayé mọ́, ẹ jẹ́ kí a gbìyànjú gbogbo agbára wa láti dìbò fún ẹni tí ó wù wá, kí gbogbo ayé sì rí i dájú pé a ṣe ẹ̀tọ́ wa.
Iṣẹ́ wà lọ́wọ́ gbogbo àwọn Oníròyìn wa o. Kí a lu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Oníròyìn wa lọ́gọ ẹnu lórí akitiyan wọn láti máa fọ̀nrere onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń lọ nínú àwùjọ wa sí etígbọ̀ọ́ wa lóòrèkóòrè.
Lára irúfẹ́ àwọn Iléeṣé Ìròyìn tí mo gbé Òṣùbà káre fún ni Ìwé Ìròyìn Awíkonko àti Oríyọmí Hamzat. Wọ́n ń gbìyànjú òtítọ́ ṣíṣe nípa àwọn Ìròyìn tí a ń gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wọn. Iléeṣé wọn kò ní jóná láṣẹ Èdùmàrè.
Lónìí, àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè ń múra sílẹ̀ fún ìdìbò tí wọ́n fẹ́ fi yan àwọn Adarí Orílẹ̀-èdè wọn, ní èyí tí ó jẹ́ ohun-èlò láti yangàn pé wọ́n ṣe ojúṣe wọn. Kí àwọn Àjọ Ètò-Ìdìbò má fi ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn dùn wọ́n lásìkò ìdìbò náà.
Ó yẹ kí a tún gba àwọn Ọ̀dọ́ ìlú wa ní ìmọ̀ràn gidi láti jáwọ́ nínú gbogbo ìwà búrúkú tí ó lè ṣe okùnfà ìdàlúrú, ìwà jàgídíjàgan àti àwọn ìwà ìpànilára mìíràn lásìkò ìdìbò náà. Kò yẹ kí a máa hu ìwà ọmọ ìsọta lẹ́yìn àwọn Òṣèlú.
Ó tún ṣe pàtàkì, kí gbogbo àwọn Adarí ẹ̀sìn àwùjọ wa yìí ṣe iṣẹ́ takuntakun láti gba àdúrà àti ààwẹ̀ fún àṣeyọrí Orílẹ̀-èdè yìí. Ọlọ́run nìkan ló kù tí a lè fi ẹ̀mí tẹ̀ lórí àwọn ìṣòro wa ní Nàìjíríà tí ó a óò fi borí àwọn ìṣòro náà. Ẹ má jẹ kí ó sú wa. A óò túbọ̀ máa bẹ Ọlọ́run náà ni, kí ó bá wa mú àyípadà rere bá Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yìí. Ọlọ́run Ọba Aláṣẹ yóò sì gbọ́ àdúrà wa lásìkò tí a wà yìí. Àmí.
Kí gbogbo ẹ̀yin Oníròyìn wa náà má bẹ̀rù láti máa bá wa gbé Ìròyìn òótọ́ jáde, kí á lè máa mọ ibi tí ọ̀rọ̀ wa kú sí ní Nàìjíríà.
Ẹ má gbé Ìròyìn tí yóò máa ṣe àpọ́nlé àwọn Òṣèlú jáde, kí ẹ máa fi àléébù wọn pamọ́. Gbogbo ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ ni kí ẹ máa fi tó wa létí ní gbogbo ìgbà. Ọlọ́run yóò sì máa fún yín ṣe láṣẹ Èdùmàrè.
Ẹ ṣeun oo.
Láìpẹ́, Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò tùbà tùṣẹ oo. Àmí.
...mo dákẹ́ díẹ̀ ná...
...mo sì fi ìyókù síkùn bí àwọn àgbààgbà...
Mo júbà oo
Ìbà Ọlọ́run Èdùmàrè
Ìbà Kábíèsí Ọlọ́tà Odò
Ìbà Ọkùnrin
Ìbà Obìnrin
Ìbà Ọmọdé
Ìbà ẹ̀yin àgbààgbà
Ẹ jẹ́ kó yẹ mí oo.
©
ÌȘỌ̀LÁ Sauban Àlàdé Orí-Àrán lèmi ń jẹ́
Ẹ̀ṣọ́ Ọmọ Ọlọ́tà Odò
👏🙇♂️👏
No comments:
Post a Comment