O ṣee ṣe ki ọwọngogo epo rọbii ṣakoba fun eto idibo ọdun 2023, ṣugbọn... - INEC pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 1, 2023

O ṣee ṣe ki ọwọngogo epo rọbii ṣakoba fun eto idibo ọdun 2023, ṣugbọn... - INEC pariwo sita


Alaga ajọ eleto idibo lorileede Naijiria, 
Independent National Electoral Commission (INEC), Mahmood Yakubu ti sọ pe o ṣee ṣe ki ọwọngogo epo rọbii to wa nita lasiko yii ṣakoba nla fun eto idibo to n bọ lọna lọjọ karundinlọgbọn oṣu keji ati ọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun 2023 ti a wa yii.

Yakubu sọ pe ipenija t'awọn araalu n koju ni ajọ INEC naa n koju lasiko yii, to si ni bi ijọba ko ba tete wa nnkan ṣe sii, afaimọ ni ki eto idibo naa ma ni kọlọfin ninu.

Nibi ipade ti alaga ajọ INEC naa ṣe pẹlu awọn ẹgbẹ awakọ bii Nigerian Association of Road Transport Owners (NARTO); National Union of Road Transport Workers (NURTW), atawọn miran lo ti jẹ ko di mimọ.

Yakubu tẹsiwaju pe oun yoo ṣe ipade papọ pẹlu ileeṣẹ to n ri sọrọ epo rọbii lorileede Naijiria, iyẹn Nigerian National Petroleum Company (NNPC) Limited lati wa ọna abayọ.

"Iṣoro ti ẹ n koju ni awa naa n koju nipa iṣoro aisi epo rọbii lorileede yii, ati ipa ti yoo ko lọjọ idibo.

"Otitọ ibẹ ni pe gbogbo eto ati ilana ti a la kalẹ ni ọwọngogo ati aisi epo rọbii ni yoo ṣakoba fun.

"Fun idi eyi, ajọ INEC yoo ṣe ipade pọ pẹlu awọn alaṣẹ NNPC lati wa ọna abayọ si ohun to wa nilẹ yii.*

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI