Iranṣẹ Ọlọrun to gbe aworan iku rẹ sita nitori ko fẹẹ san gbese miliọnu mẹta naira to jẹ dero ile ẹjọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 3, 2023

Iranṣẹ Ọlọrun to gbe aworan iku rẹ sita nitori ko fẹẹ san gbese miliọnu mẹta naira to jẹ dero ile ẹjọ


Kani ọkunrin kan ti wọn pe ni iranṣẹ Ọlọrun mọ pe iwa toun fẹẹ hu yoo pada gbe pun de ile ẹjọ ati atimọle ni, boya ni ko ba ti roo daadaa lẹẹmeji ko to gbe igbesẹ naa.
 
Iranṣẹ Ọlọrun naa, Paul Oyewọle la gbọ pe o gbe aworan ara rẹ sita, eyi to fi kede iku rẹ sori ikanni ayelujara.
 
A gbọ pe kii ṣe pe Paul deedee gbe igbesẹ naa, bi ko ṣe pe lati tan ẹnikan to jẹ ni gbese miliọnu mẹta naira jẹ, wi pe oun ti ku, lo fa a.
 
Wọn ni Paul lọ ya miliọnu mẹta naira lọwọ Emmanuel Boyede, pẹlu ileri wi pe oun yoo da owo naa pada lẹyin ọjọ meje, ṣugbọn ti ko san owo ọhun pada.
 
Iroyin ti a gbọ ni pe ṣe ni Paul bẹrẹ sii fi fọto ara rẹ sita wi pe oun ti jade laye, to si tun n fi ayederu owo ranṣẹ s'awọn to ya owo lọwọ wọn wi pe oun ti san owo naa.

Aarin ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2021 si ọjọ keje, oṣu karun-un, ọdun 2022 lo ṣẹ ẹṣẹ naa, eyi ti wọn lo tako iwe ofin ọdaran ipinlẹ naa t'ọdun 2006.
 
Paul nigba to n sọrọ niwaju adajọ, sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
 
Onidajọ ile-ẹjọ Majisireeti, Onidajọ Mosunmọla Ikujuni wa paṣẹ pe ki wọn gba beeli Paul pẹlu miliọnu kan naira, ati oniduro meji ọtọọtọ ti ile wọn ko jinna si ayika kootu, wọn si gbọdọ jẹ lanlọọdu, bakan naa ni wọn gbọdọ ẹda fi kaadi idanimọ wọn silẹ, bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI