Nitori ẹsun ipaniyan, Adajọ ni ki wọn lọ yẹgi fun ọlọpaa 'SARS' meji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 3, 2023

Nitori ẹsun ipaniyan, Adajọ ni ki wọn lọ yẹgi fun ọlọpaa 'SARS' meji


Ile ẹjọ giga to wa nipinlẹ Port Harcourt ti paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun awọn ọlọpaa ẹṣin-o-kọku, iyẹn Special Anti Robbery Squad, ti ọpọ awọn eeyan mọ si SARS 
tẹlẹ meji kan, titi ẹmi yoo fi bọ lara wọn.
 
Bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa SARS ti wọn ti wọgile naa marun-un ni wọn n jẹjọ lọwọ lori ẹsun ipaniyan, idigunjale ati ilọnilọwọ gba, ṣugbọn ti meji ti ku ninu wọn.
 
Magus Awuri ati Shedrack Ibibo lawọn mejeeji ti Onidajọ M.O Opara paṣẹ yiyẹgi fun wọn.
 
Awọn marun-un ti a gbọ pe wọn fẹsun kan naa ni Shedrack Ibibo, ASP Samuel Chigbu, Magus Awuri, Olisa Emeka ati Ogoligo, lori ẹsun wi pe wọn pa Michael Igwe ati Michael Akor lakoko ti wọn wa lahaamọ wọn.
 
Ẹsun ti wọn fi kan awọn mejeeji ni pe wọn ji kaadi ipe [recharge cards] lọdun 2015 n'ijọba ibilẹ Oyigbo, ipinlẹ Port Harcourt.
 
A gbọ pe bi ẹjọ naa ṣe n lọ lọwọ ni kootu, ni Ogoligo ati ASP Samuel Chigbu ku s'ọgba ẹwọn ti wọn ko wọn si.
 
Eyi lo mu ki Shedrack Ibibo, Olisa Emeka ati Magus Awuri tẹsiwaju ninu ẹjọ ẹsun ti wọn fi kan wọn.
 
Nigba ti Onidajọ M.O Opara, da ẹjọ iku fun Magus Awuri ati Shedrack Ibibo, Onidajọ naa tun da Olisa Emeka lare wi pe ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan an.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI