Lanre Shittu, gbajugbaja oniṣowo l'Ekoo jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 27, 2023

Lanre Shittu, gbajugbaja oniṣowo l'Ekoo jade laye


Gbajugbaja oniṣowo ọkọ ati eroja ara ọkọ niluu Eko, Ọgbẹni Lanre Shittu ti jade laye.
 
Oni, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2023 ni Shittu jade laye lẹni ọdun marundinlaadọrin, gẹgẹ bi a ṣe gbọ

Odu ni Shittu jẹ, kii ṣaimọ foloko, to si gbajumọ daadaa nigboro ilu Eko ati agbegbe ẹ, paapaa lorileede Naijiria.

Shittu gẹgẹ ni a ṣe gbọ lo wa ni ipo akọkọ nilẹ Afrika ninu awọn oniṣowo to maa n ko awọn tirela Mack wọle lato ta a ni Naijiria.
 
Oloogbe yii lo tun gba iwe aṣẹ lati ta awọn mọto ileeṣẹ KIA, NISSAN, Bọọsi Jinbei, to si tun jẹ gbajugbaja ninu awọn to n ta eroja ara ọkọ kaakiri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI