Awọn tọọgi kọlu ibudo idibo, wọn yinbọn pa iya ọlọmọ mẹta danu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 27, 2023

Awọn tọọgi kọlu ibudo idibo, wọn yinbọn pa iya ọlọmọ mẹta danu


Kani iyaale ile ẹni ọdun mọkanlelogoji yii, Elizabeth Arigo Owie mọ pe opin ọsẹ to kọja yii ni yoo jẹ igbẹyin oun loke eepẹ ni, boya ko ba ti jokoo rẹ sile jẹjẹ.
 
Nibi ti awọn tọọgi ti da wahala silẹ lawọn ibudo idibo kan lagbegbe Ogheghe, ijọba ibilẹ Ikpoba Okha, niluu Benin la gbọ pe ọta ibọn ti ba Elizabeth, iya ọlọmọ mẹta, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 

 
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe wọn ti kọkọ gun obinrin  kan, Efidi Bina Jennifer, nijọba ibilẹ Surulere l'Ekoo, iyẹn nibi t'awọn tọọgi ti da wahala silẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI